Quran Apps in many lanuages:

Surah Aal-E-Imran Ayahs #168 Translated in Yoruba

لَقَدْ مَنَّ اللَّهُ عَلَى الْمُؤْمِنِينَ إِذْ بَعَثَ فِيهِمْ رَسُولًا مِنْ أَنْفُسِهِمْ يَتْلُو عَلَيْهِمْ آيَاتِهِ وَيُزَكِّيهِمْ وَيُعَلِّمُهُمُ الْكِتَابَ وَالْحِكْمَةَ وَإِنْ كَانُوا مِنْ قَبْلُ لَفِي ضَلَالٍ مُبِينٍ
Allahu kuku ti se oore fun awon onigbagbo ododo nigba ti O fi le gbe Ojise kan dide si won laaarin ara won. (Ojise naa) n ke awon ayah Re fun won. O n fo won mo (ninu ese). O si n ko won ni Tira (al-Ƙur’an) ati ijinle oye (sunnah), bi o tile je pe teletele won wa ninu isina ponnbele
أَوَلَمَّا أَصَابَتْكُمْ مُصِيبَةٌ قَدْ أَصَبْتُمْ مِثْلَيْهَا قُلْتُمْ أَنَّىٰ هَٰذَا ۖ قُلْ هُوَ مِنْ عِنْدِ أَنْفُسِكُمْ ۗ إِنَّ اللَّهَ عَلَىٰ كُلِّ شَيْءٍ قَدِيرٌ
Se gbogbo igba ti adanwo kan ba kan yin, ti e si ti fi meji iru re (kan awon keferi), ni eyin yoo maa so pe: “Ona wo ni eyi gba sele si wa?” So pe: “O wa lati odo ara yin.” Dajudaju Allahu ni Alagbara lori gbogbo nnkan
وَمَا أَصَابَكُمْ يَوْمَ الْتَقَى الْجَمْعَانِ فَبِإِذْنِ اللَّهِ وَلِيَعْلَمَ الْمُؤْمِنِينَ
Ohun ti o sele si yin ni ojo ti iko ogun mejeeji pade (sele) pelu iyonda Allahu. Ati pe nitori ki O le safi han awon onigbagbo ododo ni
وَلِيَعْلَمَ الَّذِينَ نَافَقُوا ۚ وَقِيلَ لَهُمْ تَعَالَوْا قَاتِلُوا فِي سَبِيلِ اللَّهِ أَوِ ادْفَعُوا ۖ قَالُوا لَوْ نَعْلَمُ قِتَالًا لَاتَّبَعْنَاكُمْ ۗ هُمْ لِلْكُفْرِ يَوْمَئِذٍ أَقْرَبُ مِنْهُمْ لِلْإِيمَانِ ۚ يَقُولُونَ بِأَفْوَاهِهِمْ مَا لَيْسَ فِي قُلُوبِهِمْ ۗ وَاللَّهُ أَعْلَمُ بِمَا يَكْتُمُونَ
(O tun ri bee) nitori ki O le safi han awon t’o sobe-selu (ninu awon musulumi). (Awon onigbagbo ododo) si so fun won pe: “E maa bo, ki a lo jagun fun esin Allahu tabi e wa daabo bo emi ara yin.” Won wi pe: “Awa iba mo ogun-un ja awa iba tele yin.” Won sunmo aigbagbo ni ojo yen ju igbagbo lo. Won n fi enu won so ohun ti ko si ninu okan won. Allahu si nimo julo nipa ohun ti won n fi pamo
الَّذِينَ قَالُوا لِإِخْوَانِهِمْ وَقَعَدُوا لَوْ أَطَاعُونَا مَا قُتِلُوا ۗ قُلْ فَادْرَءُوا عَنْ أَنْفُسِكُمُ الْمَوْتَ إِنْ كُنْتُمْ صَادِقِينَ
Awon t’o so nipa awon omo iya won (t’o ku s’oju ogun esin) pe – ti awon si jokoo kale sile (ni tiwon), "Ti o ba je pe won tele tiwa ni, won iba ti pa won." So pe: “E yeku danu fun emi yin ti e ba je olododo.”

Choose other languages: