Quran Apps in many lanuages:

Surah Aal-E-Imran Ayahs #159 Translated in Yoruba

إِنَّ الَّذِينَ تَوَلَّوْا مِنْكُمْ يَوْمَ الْتَقَى الْجَمْعَانِ إِنَّمَا اسْتَزَلَّهُمُ الشَّيْطَانُ بِبَعْضِ مَا كَسَبُوا ۖ وَلَقَدْ عَفَا اللَّهُ عَنْهُمْ ۗ إِنَّ اللَّهَ غَفُورٌ حَلِيمٌ
Dajudaju awon t’o peyin da ninu yin ni ojo ti ijo meji pade, dajudaju Esu l’o ye won lese nitori apa kan ohun ti won se nise. Allahu si kuku ti samoju kuro fun won. Dajudaju Allahu ni Alaforijin, Alafarada
يَا أَيُّهَا الَّذِينَ آمَنُوا لَا تَكُونُوا كَالَّذِينَ كَفَرُوا وَقَالُوا لِإِخْوَانِهِمْ إِذَا ضَرَبُوا فِي الْأَرْضِ أَوْ كَانُوا غُزًّى لَوْ كَانُوا عِنْدَنَا مَا مَاتُوا وَمَا قُتِلُوا لِيَجْعَلَ اللَّهُ ذَٰلِكَ حَسْرَةً فِي قُلُوبِهِمْ ۗ وَاللَّهُ يُحْيِي وَيُمِيتُ ۗ وَاللَّهُ بِمَا تَعْمَلُونَ بَصِيرٌ
Eyin ti e gbagbo ni ododo, e ma se da bi awon t’o sai gbagbo, ti won so fun awon omo iya won, nigba ti won n rin kiri ni ori ile tabi (nigba) ti won n jagun, pe: “Ti o ba je pe won n be ni odo wa ni, won iba ti ku, ati pe won iba ti pa won.” (Won wi bee) nitori ki Allahu le fi iyen se abamo sinu okan won. Allahu l’O n so eda di alaaye. O si n so eda di oku. Allahu si ni Oluriran nipa ohun ti e n se nise
وَلَئِنْ قُتِلْتُمْ فِي سَبِيلِ اللَّهِ أَوْ مُتُّمْ لَمَغْفِرَةٌ مِنَ اللَّهِ وَرَحْمَةٌ خَيْرٌ مِمَّا يَجْمَعُونَ
Dajudaju ti won ba pa yin s’oju ogun esin Allahu tabi e ku (sinu ile), dajudaju aforijin ati aanu lati odo Allahu loore ju ohun ti e n kojo (nile aye)
وَلَئِنْ مُتُّمْ أَوْ قُتِلْتُمْ لَإِلَى اللَّهِ تُحْشَرُونَ
Dajudaju ti e ba ku (sinu ile) tabi won pa yin (s’oju ogun esin), dajudaju odo Allahu ni won maa ko yin jo si
فَبِمَا رَحْمَةٍ مِنَ اللَّهِ لِنْتَ لَهُمْ ۖ وَلَوْ كُنْتَ فَظًّا غَلِيظَ الْقَلْبِ لَانْفَضُّوا مِنْ حَوْلِكَ ۖ فَاعْفُ عَنْهُمْ وَاسْتَغْفِرْ لَهُمْ وَشَاوِرْهُمْ فِي الْأَمْرِ ۖ فَإِذَا عَزَمْتَ فَتَوَكَّلْ عَلَى اللَّهِ ۚ إِنَّ اللَّهَ يُحِبُّ الْمُتَوَكِّلِينَ
Ike kan lati odo Allahu l’o kuku ro o fun won; ti o ba je pe o je eni buruku, olokan lile, won iba ti tuka kuro lodo re. Samoju kuro fun won, ba won toro aforijin, ki o si ba won jiroro lori oro. Ti o ba si pinnu (oro kan), ki o gbarale Allahu. Dajudaju Allahu nifee awon olugbarale E

Choose other languages: