Quran Apps in many lanuages:

Surah Aal-E-Imran Ayahs #117 Translated in Yoruba

لَيْسُوا سَوَاءً ۗ مِنْ أَهْلِ الْكِتَابِ أُمَّةٌ قَائِمَةٌ يَتْلُونَ آيَاتِ اللَّهِ آنَاءَ اللَّيْلِ وَهُمْ يَسْجُدُونَ
(Awon ahlul-kitab) ko ri bakan naa. Ijo kan t’o duro deede wa ninu awon ahlul-kitab, ti n ke awon ayah Allahu ni akoko oru, ti won si n fori kanle (lori irun)
يُؤْمِنُونَ بِاللَّهِ وَالْيَوْمِ الْآخِرِ وَيَأْمُرُونَ بِالْمَعْرُوفِ وَيَنْهَوْنَ عَنِ الْمُنْكَرِ وَيُسَارِعُونَ فِي الْخَيْرَاتِ وَأُولَٰئِكَ مِنَ الصَّالِحِينَ
Won gbagbo ninu Allahu ati Ojo Ikeyin. Won n pase ohun rere, won n ko ohun buruku, won si n yara nibi awon ise olooore. Awon wonyen wa ninu awon eni rere
وَمَا يَفْعَلُوا مِنْ خَيْرٍ فَلَنْ يُكْفَرُوهُ ۗ وَاللَّهُ عَلِيمٌ بِالْمُتَّقِينَ
Ohunkohun ti won ba se ni ise rere, A o nii je ki won padanu esan re. Allahu si ni Onimo nipa awon oluberu (Re)
إِنَّ الَّذِينَ كَفَرُوا لَنْ تُغْنِيَ عَنْهُمْ أَمْوَالُهُمْ وَلَا أَوْلَادُهُمْ مِنَ اللَّهِ شَيْئًا ۖ وَأُولَٰئِكَ أَصْحَابُ النَّارِ ۚ هُمْ فِيهَا خَالِدُونَ
Dajudaju awon t’o sai gbagbo, awon dukia won ati awon omo won ko nii ro won loro kini kan nibi iya lodo Allahu. Awon wonyen si ni ero inu Ina. Olusegbere ni won ninu re
مَثَلُ مَا يُنْفِقُونَ فِي هَٰذِهِ الْحَيَاةِ الدُّنْيَا كَمَثَلِ رِيحٍ فِيهَا صِرٌّ أَصَابَتْ حَرْثَ قَوْمٍ ظَلَمُوا أَنْفُسَهُمْ فَأَهْلَكَتْهُ ۚ وَمَا ظَلَمَهُمُ اللَّهُ وَلَٰكِنْ أَنْفُسَهُمْ يَظْلِمُونَ
Apejuwe ohun ti won n na ninu isemi aye yii da bi apejuwe afefe ti ategun otutu lile wa ninu re. O fe lu oko awon eniyan t’o se abosi s’ori ara won. O si pa a run. Allahu ko si se abosi si won, sugbon emi ara won ni won n sabosi si

Choose other languages: