Quran Apps in many lanuages:

Surah Aal-E-Imran Ayahs #116 Translated in Yoruba

ضُرِبَتْ عَلَيْهِمُ الذِّلَّةُ أَيْنَ مَا ثُقِفُوا إِلَّا بِحَبْلٍ مِنَ اللَّهِ وَحَبْلٍ مِنَ النَّاسِ وَبَاءُوا بِغَضَبٍ مِنَ اللَّهِ وَضُرِبَتْ عَلَيْهِمُ الْمَسْكَنَةُ ۚ ذَٰلِكَ بِأَنَّهُمْ كَانُوا يَكْفُرُونَ بِآيَاتِ اللَّهِ وَيَقْتُلُونَ الْأَنْبِيَاءَ بِغَيْرِ حَقٍّ ۚ ذَٰلِكَ بِمَا عَصَوْا وَكَانُوا يَعْتَدُونَ
Abuku yoo maa ba won nibikibi ti owo awon (musulumi) ba ti ba won afi (ti won ba n be) pelu aabo lati odo Allahu (iyen ni pe, ki won gba ’Islam) ati aabo lati odo awon eniyan (iyen ni pe, ki won gba lati maa san owo isakole fun ijoba ’Islam). Won seri pada pelu ibinu lati odo Allahu. Won si ko osi ba won. Iyen nitori pe, dajudaju won sai gbagbo ninu awon ayah Allahu, won tun n pa awon Anabi lai letoo. Iyen nitori pe, won yapa (ase Allahu), won si n tayo enu ala
لَيْسُوا سَوَاءً ۗ مِنْ أَهْلِ الْكِتَابِ أُمَّةٌ قَائِمَةٌ يَتْلُونَ آيَاتِ اللَّهِ آنَاءَ اللَّيْلِ وَهُمْ يَسْجُدُونَ
(Awon ahlul-kitab) ko ri bakan naa. Ijo kan t’o duro deede wa ninu awon ahlul-kitab, ti n ke awon ayah Allahu ni akoko oru, ti won si n fori kanle (lori irun)
يُؤْمِنُونَ بِاللَّهِ وَالْيَوْمِ الْآخِرِ وَيَأْمُرُونَ بِالْمَعْرُوفِ وَيَنْهَوْنَ عَنِ الْمُنْكَرِ وَيُسَارِعُونَ فِي الْخَيْرَاتِ وَأُولَٰئِكَ مِنَ الصَّالِحِينَ
Won gbagbo ninu Allahu ati Ojo Ikeyin. Won n pase ohun rere, won n ko ohun buruku, won si n yara nibi awon ise olooore. Awon wonyen wa ninu awon eni rere
وَمَا يَفْعَلُوا مِنْ خَيْرٍ فَلَنْ يُكْفَرُوهُ ۗ وَاللَّهُ عَلِيمٌ بِالْمُتَّقِينَ
Ohunkohun ti won ba se ni ise rere, A o nii je ki won padanu esan re. Allahu si ni Onimo nipa awon oluberu (Re)
إِنَّ الَّذِينَ كَفَرُوا لَنْ تُغْنِيَ عَنْهُمْ أَمْوَالُهُمْ وَلَا أَوْلَادُهُمْ مِنَ اللَّهِ شَيْئًا ۖ وَأُولَٰئِكَ أَصْحَابُ النَّارِ ۚ هُمْ فِيهَا خَالِدُونَ
Dajudaju awon t’o sai gbagbo, awon dukia won ati awon omo won ko nii ro won loro kini kan nibi iya lodo Allahu. Awon wonyen si ni ero inu Ina. Olusegbere ni won ninu re

Choose other languages: