Quran Apps in many lanuages:

Surah Aal-E-Imran Ayahs #14 Translated in Yoruba

إِنَّ الَّذِينَ كَفَرُوا لَنْ تُغْنِيَ عَنْهُمْ أَمْوَالُهُمْ وَلَا أَوْلَادُهُمْ مِنَ اللَّهِ شَيْئًا ۖ وَأُولَٰئِكَ هُمْ وَقُودُ النَّارِ
Dajudaju awon t’o sai gbagbo, awon dukia won ati awon omo won ko nii ro won loro kini kan lodo Allahu. Awon wonyen, awon ni nnkan ikona
كَدَأْبِ آلِ فِرْعَوْنَ وَالَّذِينَ مِنْ قَبْلِهِمْ ۚ كَذَّبُوا بِآيَاتِنَا فَأَخَذَهُمُ اللَّهُ بِذُنُوبِهِمْ ۗ وَاللَّهُ شَدِيدُ الْعِقَابِ
(Isesi won) da bi isesi awon eniyan Fir‘aon ati awon t’o siwaju won, ti won pe awon ayah Wa niro. Nitori naa, Allahu mu won nitori ese won. Allahu si le nibi iya
قُلْ لِلَّذِينَ كَفَرُوا سَتُغْلَبُونَ وَتُحْشَرُونَ إِلَىٰ جَهَنَّمَ ۚ وَبِئْسَ الْمِهَادُ
So fun awon t’o sai gbagbo pe: "Won maa segun yin. Won si maa ko yin jo sinu ina Jahanamo. Ibugbe naa si buru
قَدْ كَانَ لَكُمْ آيَةٌ فِي فِئَتَيْنِ الْتَقَتَا ۖ فِئَةٌ تُقَاتِلُ فِي سَبِيلِ اللَّهِ وَأُخْرَىٰ كَافِرَةٌ يَرَوْنَهُمْ مِثْلَيْهِمْ رَأْيَ الْعَيْنِ ۚ وَاللَّهُ يُؤَيِّدُ بِنَصْرِهِ مَنْ يَشَاءُ ۗ إِنَّ فِي ذَٰلِكَ لَعِبْرَةً لِأُولِي الْأَبْصَارِ
Ami kuku wa fun yin nibi awon ijo meji ti won pade (ara won). Ijo kan n ja fun aabo esin Allahu. Ikeji si je alaigbagbo. Ijo keji n ri ijo kiini bi ilopo meji won ni riri oju. Allahu n fi aranse Re se ikunlowo fun eni ti O ba fe. Dajudaju ariwoye wa ninu iyen fun awon oluriran
زُيِّنَ لِلنَّاسِ حُبُّ الشَّهَوَاتِ مِنَ النِّسَاءِ وَالْبَنِينَ وَالْقَنَاطِيرِ الْمُقَنْطَرَةِ مِنَ الذَّهَبِ وَالْفِضَّةِ وَالْخَيْلِ الْمُسَوَّمَةِ وَالْأَنْعَامِ وَالْحَرْثِ ۗ ذَٰلِكَ مَتَاعُ الْحَيَاةِ الدُّنْيَا ۖ وَاللَّهُ عِنْدَهُ حُسْنُ الْمَآبِ
Won se e ni oso fun awon eniyan; ife igbadun lara awon obinrin, awon omokunrin, awon owo wura ati fadaka pupo ati awon esin ti won se ni oso, awon eran-osin ati (nnkan) oko. Iyen ni nnkan igbaye-gbadun. Odo Allahu si ni abo rere wa

Choose other languages: