Quran Apps in many lanuages:

Surah Aal-E-Imran Ayahs #107 Translated in Yoruba

وَاعْتَصِمُوا بِحَبْلِ اللَّهِ جَمِيعًا وَلَا تَفَرَّقُوا ۚ وَاذْكُرُوا نِعْمَتَ اللَّهِ عَلَيْكُمْ إِذْ كُنْتُمْ أَعْدَاءً فَأَلَّفَ بَيْنَ قُلُوبِكُمْ فَأَصْبَحْتُمْ بِنِعْمَتِهِ إِخْوَانًا وَكُنْتُمْ عَلَىٰ شَفَا حُفْرَةٍ مِنَ النَّارِ فَأَنْقَذَكُمْ مِنْهَا ۗ كَذَٰلِكَ يُبَيِّنُ اللَّهُ لَكُمْ آيَاتِهِ لَعَلَّكُمْ تَهْتَدُونَ
E duro sinsin ti okun Allahu (’Islam) ni apapo, e ma se pin si ijo otooto. Ki e si ranti ike Allahu ti n be lori yin (pe) nigba ti e je ota (ara yin nigba aimokan), O pa okan yin po mora won (pelu ’Islam), e si di omo iya pelu ike Re; ati (nigba ti) e wa leti ogbun Ina, O gba yin la kuro ninu re. Bayen ni Allahu se n se alaye awon ayah Re fun yin nitori ki e le mona (’Islam)
وَلْتَكُنْ مِنْكُمْ أُمَّةٌ يَدْعُونَ إِلَى الْخَيْرِ وَيَأْمُرُونَ بِالْمَعْرُوفِ وَيَنْهَوْنَ عَنِ الْمُنْكَرِ ۚ وَأُولَٰئِكَ هُمُ الْمُفْلِحُونَ
Ki o maa be ninu yin, ijo kan ti yoo maa pepe sibi ohun t’o loore julo, won yoo maa pase ohun rere, won yo si maa ko ohun buruku. Awon wonyen, awon si ni olujere
وَلَا تَكُونُوا كَالَّذِينَ تَفَرَّقُوا وَاخْتَلَفُوا مِنْ بَعْدِ مَا جَاءَهُمُ الْبَيِّنَاتُ ۚ وَأُولَٰئِكَ لَهُمْ عَذَابٌ عَظِيمٌ
E ma se da bi awon t’o sora won di ijo otooto, ti won si yapa enu (si ’Islam) leyin ti awon alaye t’o yanju ti de ba won. Awon wonyen si ni iya nla n be fun
يَوْمَ تَبْيَضُّ وُجُوهٌ وَتَسْوَدُّ وُجُوهٌ ۚ فَأَمَّا الَّذِينَ اسْوَدَّتْ وُجُوهُهُمْ أَكَفَرْتُمْ بَعْدَ إِيمَانِكُمْ فَذُوقُوا الْعَذَابَ بِمَا كُنْتُمْ تَكْفُرُونَ
Ni ojo ti awon oju kan yoo funfun (imole). Awon oju kan yo si dudu. Ni ti awon ti oju won dudu, (A o bi won pe:) "Se e sai gbagbo leyin igbagbo yin ni?" Nitori naa, e to iya wo nitori pe e sai gbagbo
وَأَمَّا الَّذِينَ ابْيَضَّتْ وُجُوهُهُمْ فَفِي رَحْمَةِ اللَّهِ هُمْ فِيهَا خَالِدُونَ
Ni ti awon ti oju won funfun (imole), ninu ike Allahu ni won yoo wa. Olusegbere ni won ninu re

Choose other languages: