Quran Apps in many lanuages:

Surah Yusuf Ayahs #70 Translated in Yoruba

قَالَ لَنْ أُرْسِلَهُ مَعَكُمْ حَتَّىٰ تُؤْتُونِ مَوْثِقًا مِنَ اللَّهِ لَتَأْتُنَّنِي بِهِ إِلَّا أَنْ يُحَاطَ بِكُمْ ۖ فَلَمَّا آتَوْهُ مَوْثِقَهُمْ قَالَ اللَّهُ عَلَىٰ مَا نَقُولُ وَكِيلٌ
O so pe: “Emi ko nii je ki o ba yin lo titi e maa fi se adehun fun mi ni (oruko) Allahu pe dajudaju e maa mu un pada wa ba mi afi ti (awon ota) ba ka yin mo.” Nigba ti won fun un ni adehun won tan, o so pe: “Allahu ni Elerii lori ohun ti a n so (yii).”
وَقَالَ يَا بَنِيَّ لَا تَدْخُلُوا مِنْ بَابٍ وَاحِدٍ وَادْخُلُوا مِنْ أَبْوَابٍ مُتَفَرِّقَةٍ ۖ وَمَا أُغْنِي عَنْكُمْ مِنَ اللَّهِ مِنْ شَيْءٍ ۖ إِنِ الْحُكْمُ إِلَّا لِلَّهِ ۖ عَلَيْهِ تَوَكَّلْتُ ۖ وَعَلَيْهِ فَلْيَتَوَكَّلِ الْمُتَوَكِّلُونَ
O tun so pe: “Eyin omo mi, e ma se gba enu ona eyo kan wole. E gba enu ona otooto wole. Emi ko le fi nnkan kan ro yin loro lodo Allahu. Ko si idajo (fun eni kan) afi fun Allahu. Oun ni mo gbarale. Oun si ni ki awon olugbarale gbarale.”
وَلَمَّا دَخَلُوا مِنْ حَيْثُ أَمَرَهُمْ أَبُوهُمْ مَا كَانَ يُغْنِي عَنْهُمْ مِنَ اللَّهِ مِنْ شَيْءٍ إِلَّا حَاجَةً فِي نَفْسِ يَعْقُوبَ قَضَاهَا ۚ وَإِنَّهُ لَذُو عِلْمٍ لِمَا عَلَّمْنَاهُ وَلَٰكِنَّ أَكْثَرَ النَّاسِ لَا يَعْلَمُونَ
Nigba ti won wo (inu ilu) ni awon aye ti baba won pa lase fun won, ko si ro won loro kan kan lodo Allahu bi ko se bukata kan ninu emi (Anabi) Ya‘ƙub ti o muse. Dajudaju onimo ni nipa ohun ti A fi mo on, sugbon opolopo awon eniyan ko mo
وَلَمَّا دَخَلُوا عَلَىٰ يُوسُفَ آوَىٰ إِلَيْهِ أَخَاهُ ۖ قَالَ إِنِّي أَنَا أَخُوكَ فَلَا تَبْتَئِسْ بِمَا كَانُوا يَعْمَلُونَ
Nigba ti won wole ti (Anabi) Yusuf, o mu omo-iya re mora sodo re. O so pe: “Dajudaju emi ni omo-iya re. Nitori naa, ma se banuje nipa ohun ti won n se nise.”
فَلَمَّا جَهَّزَهُمْ بِجَهَازِهِمْ جَعَلَ السِّقَايَةَ فِي رَحْلِ أَخِيهِ ثُمَّ أَذَّنَ مُؤَذِّنٌ أَيَّتُهَا الْعِيرُ إِنَّكُمْ لَسَارِقُونَ
Nigba ti o si ba won di eru won tan, o fi ife-imumi sinu eru omo-iya re. Leyin naa, olupepe kan kede pe: “Eyin ero-rakunmi, dajudaju eyin ni ole.”

Choose other languages: