Quran Apps in many lanuages:

Surah Yunus Ayahs #102 Translated in Yoruba

فَلَوْلَا كَانَتْ قَرْيَةٌ آمَنَتْ فَنَفَعَهَا إِيمَانُهَا إِلَّا قَوْمَ يُونُسَ لَمَّا آمَنُوا كَشَفْنَا عَنْهُمْ عَذَابَ الْخِزْيِ فِي الْحَيَاةِ الدُّنْيَا وَمَتَّعْنَاهُمْ إِلَىٰ حِينٍ
Ko kuku si ilu kan, t’o gbagbo (lasiko iya), ti igbagbo re si se e ni anfaani afi ijo (Anabi) Yunus. Nigba ti won gbagbo, A mu abuku iya kuro fun won ninu isemi aye. A si je ki won je igbadun aye fun igba die
وَلَوْ شَاءَ رَبُّكَ لَآمَنَ مَنْ فِي الْأَرْضِ كُلُّهُمْ جَمِيعًا ۚ أَفَأَنْتَ تُكْرِهُ النَّاسَ حَتَّىٰ يَكُونُوا مُؤْمِنِينَ
Ti o ba je pe Oluwa re ba fe, awon ti n be lori ile iba gbagbo, gbogbo won patapata. Nitori naa, se iwo l’o maa je won nipa ni titi won yoo fi di onigbagbo ododo
وَمَا كَانَ لِنَفْسٍ أَنْ تُؤْمِنَ إِلَّا بِإِذْنِ اللَّهِ ۚ وَيَجْعَلُ الرِّجْسَ عَلَى الَّذِينَ لَا يَعْقِلُونَ
Emi kan ko le gbagbo afi pelu ase Allahu. O si maa fi iya je awon ti ko se laakaye
قُلِ انْظُرُوا مَاذَا فِي السَّمَاوَاتِ وَالْأَرْضِ ۚ وَمَا تُغْنِي الْآيَاتُ وَالنُّذُرُ عَنْ قَوْمٍ لَا يُؤْمِنُونَ
So pe: "E woye si nnkan ti n be ninu sanmo ati ile. Awon ayah ati ikilo ko si nii ro ijo alaigbagbo loro
فَهَلْ يَنْتَظِرُونَ إِلَّا مِثْلَ أَيَّامِ الَّذِينَ خَلَوْا مِنْ قَبْلِهِمْ ۚ قُلْ فَانْتَظِرُوا إِنِّي مَعَكُمْ مِنَ الْمُنْتَظِرِينَ
Nitori naa, se won tun n reti (nnkan miiran) ni bi ko se (iparun) iru ti igba awon t’o re koja lo siwaju won. So pe: “E maa reti nigba naa. Dajudaju emi naa wa pelu yin ninu awon olureti.”

Choose other languages: