Quran Apps in many lanuages:

Surah Yunus Ayahs #57 Translated in Yoruba

وَيَسْتَنْبِئُونَكَ أَحَقٌّ هُوَ ۖ قُلْ إِي وَرَبِّي إِنَّهُ لَحَقٌّ ۖ وَمَا أَنْتُمْ بِمُعْجِزِينَ
Won si n beere fun iro re lodo re pe, “se ododo ni?” So pe: “Bee ni. Mo fi Oluwa mi bura. Dajudaju ododo ni. Eyin ko si nii mori bo.”
وَلَوْ أَنَّ لِكُلِّ نَفْسٍ ظَلَمَتْ مَا فِي الْأَرْضِ لَافْتَدَتْ بِهِ ۗ وَأَسَرُّوا النَّدَامَةَ لَمَّا رَأَوُا الْعَذَابَ ۖ وَقُضِيَ بَيْنَهُمْ بِالْقِسْطِ ۚ وَهُمْ لَا يُظْلَمُونَ
Ati pe ti o ba je pe gbogbo nnkan ti n be lori ile je ti emi kookan t’o sabosi, iba fi serapada (fun emi ara won nibi iya). Won yoo fi igbe abamo pamo nigba ti won ba ri Iya. A o se idajo laaarin won pelu deede; Won ko si nii sabosi si won
أَلَا إِنَّ لِلَّهِ مَا فِي السَّمَاوَاتِ وَالْأَرْضِ ۗ أَلَا إِنَّ وَعْدَ اللَّهِ حَقٌّ وَلَٰكِنَّ أَكْثَرَهُمْ لَا يَعْلَمُونَ
Gbo, dajudaju ti Allahu ni ohunkohun t’o wa ninu awon sanmo ati ile. Gbo! Dajudaju adehun Allahu ni ododo, sugbon opolopo won ko nimo
هُوَ يُحْيِي وَيُمِيتُ وَإِلَيْهِ تُرْجَعُونَ
O n so eda di alaaye. O si n so eda di oku. Odo Re si ni won yoo da yin pada si
يَا أَيُّهَا النَّاسُ قَدْ جَاءَتْكُمْ مَوْعِظَةٌ مِنْ رَبِّكُمْ وَشِفَاءٌ لِمَا فِي الصُّدُورِ وَهُدًى وَرَحْمَةٌ لِلْمُؤْمِنِينَ
Eyin eniyan, isiti kan lati odo Oluwa yin ti de ba yin. Iwosan ni fun nnkan t’o wa ninu awon igba-aya eda. Imona ati ike ni fun awon onigbagbo ododo

Choose other languages: