Quran Apps in many lanuages:

Surah Saba Ayahs #12 Translated in Yoruba

أَفْتَرَىٰ عَلَى اللَّهِ كَذِبًا أَمْ بِهِ جِنَّةٌ ۗ بَلِ الَّذِينَ لَا يُؤْمِنُونَ بِالْآخِرَةِ فِي الْعَذَابِ وَالضَّلَالِ الْبَعِيدِ
Se o da adapa iro mo Allahu ni tabi alujannu n be lara re ni?” Rara o! Awon ti ko gba Ojo Ikeyin gbo ti wa ninu iya ati isina t’o jinna
أَفَلَمْ يَرَوْا إِلَىٰ مَا بَيْنَ أَيْدِيهِمْ وَمَا خَلْفَهُمْ مِنَ السَّمَاءِ وَالْأَرْضِ ۚ إِنْ نَشَأْ نَخْسِفْ بِهِمُ الْأَرْضَ أَوْ نُسْقِطْ عَلَيْهِمْ كِسَفًا مِنَ السَّمَاءِ ۚ إِنَّ فِي ذَٰلِكَ لَآيَةً لِكُلِّ عَبْدٍ مُنِيبٍ
Se won ko ri ohun t’o n be niwaju won ati ohun t’o n be leyin won ni sanmo ati ile? Ti A ba fe, Awa iba je ki ile ri mo won lese, tabi ki A ja apa kan sanmo lule le won lori mole. Dajudaju ami kan wa ninu iyen fun gbogbo erusin, oluronupiwada
وَلَقَدْ آتَيْنَا دَاوُودَ مِنَّا فَضْلًا ۖ يَا جِبَالُ أَوِّبِي مَعَهُ وَالطَّيْرَ ۖ وَأَلَنَّا لَهُ الْحَدِيدَ
Dajudaju A ti fun (Anabi) Dawud ni oore ajulo lati odo Wa; Eyin apata, e se afomo pelu re. (A pe) awon eye naa (pe ki won se bee.) A si ro irin fun un
أَنِ اعْمَلْ سَابِغَاتٍ وَقَدِّرْ فِي السَّرْدِ ۖ وَاعْمَلُوا صَالِحًا ۖ إِنِّي بِمَا تَعْمَلُونَ بَصِيرٌ
(A so fun un) pe se awon ewu irin t’o maa bo ara, se oruka-orun fun ewu irin naa niwon-niwon. Ki e si se rere. Dajudaju Emi ni Oluriran nipa ohun ti e n se nise
وَلِسُلَيْمَانَ الرِّيحَ غُدُوُّهَا شَهْرٌ وَرَوَاحُهَا شَهْرٌ ۖ وَأَسَلْنَا لَهُ عَيْنَ الْقِطْرِ ۖ وَمِنَ الْجِنِّ مَنْ يَعْمَلُ بَيْنَ يَدَيْهِ بِإِذْنِ رَبِّهِ ۖ وَمَنْ يَزِغْ مِنْهُمْ عَنْ أَمْرِنَا نُذِقْهُ مِنْ عَذَابِ السَّعِيرِ
Ati pe (A te) ategun lori ba fun (Anabi) Sulaemon, irin osu kan ni irin owuro re, irin osu kan si ni irin irole re . A si mu ki odo ide maa san ninu ile fun un. O si wa ninu awon alujannu, eyi t’o n sise (fun un) niwaju re pelu iyonda Oluwa re. Ati pe eni ti o ba gbunri kuro nibi ase Wa ninu won, A maa fun un ni iya ina t’o n jo fofo to wo

Choose other languages: