Quran Apps in many lanuages:

Surah Saba Ayahs #43 Translated in Yoruba

قُلْ إِنَّ رَبِّي يَبْسُطُ الرِّزْقَ لِمَنْ يَشَاءُ مِنْ عِبَادِهِ وَيَقْدِرُ لَهُ ۚ وَمَا أَنْفَقْتُمْ مِنْ شَيْءٍ فَهُوَ يُخْلِفُهُ ۖ وَهُوَ خَيْرُ الرَّازِقِينَ
So pe: “Dajudaju Oluwa mi, O n te arisiki sile fun eni ti O ba fe. O si n diwon re fun elomiiran. Ati pe ohunkohun ti e ba na, Oun l’O maa fi (omiran) ropo re. O si l’oore julo ninu awon olupese.”
وَيَوْمَ يَحْشُرُهُمْ جَمِيعًا ثُمَّ يَقُولُ لِلْمَلَائِكَةِ أَهَٰؤُلَاءِ إِيَّاكُمْ كَانُوا يَعْبُدُونَ
Ni ojo ti Allahu yoo ko gbogbo won jo patapata, leyin naa O maa so fun awon molaika pe: “Se eyin ni won n josin fun?”
قَالُوا سُبْحَانَكَ أَنْتَ وَلِيُّنَا مِنْ دُونِهِمْ ۖ بَلْ كَانُوا يَعْبُدُونَ الْجِنَّ ۖ أَكْثَرُهُمْ بِهِمْ مُؤْمِنُونَ
Won a so pe: “Mimo fun O! Iwo ni Alaabo wa, ki i se awon. Rara (won ko josin fun wa). Awon alujannu ni won n josin fun; opolopo won ni won gba alujannu gbo
فَالْيَوْمَ لَا يَمْلِكُ بَعْضُكُمْ لِبَعْضٍ نَفْعًا وَلَا ضَرًّا وَنَقُولُ لِلَّذِينَ ظَلَمُوا ذُوقُوا عَذَابَ النَّارِ الَّتِي كُنْتُمْ بِهَا تُكَذِّبُونَ
Nitori naa, ni oni apa kan yin ko ni ikapa anfaani, ko si ni ikapa inira fun apa kan. A si maa so fun awon t’o sabosi pe: “E to iya Ina ti e n pe niro wo.”
وَإِذَا تُتْلَىٰ عَلَيْهِمْ آيَاتُنَا بَيِّنَاتٍ قَالُوا مَا هَٰذَا إِلَّا رَجُلٌ يُرِيدُ أَنْ يَصُدَّكُمْ عَمَّا كَانَ يَعْبُدُ آبَاؤُكُمْ وَقَالُوا مَا هَٰذَا إِلَّا إِفْكٌ مُفْتَرًى ۚ وَقَالَ الَّذِينَ كَفَرُوا لِلْحَقِّ لَمَّا جَاءَهُمْ إِنْ هَٰذَا إِلَّا سِحْرٌ مُبِينٌ
Ati pe nigba ti won ba n ke awon ayah Wa t’o yanju fun won, won a wi pe: “Ki ni eyi bi ko se okunrin kan ti o fe se yin lori kuro nibi nnkan ti awon baba yin n josin fun.” Won tun wi pe: “Ki ni eyi bi ko se adapa iro.” Ati pe awon t’o sai gbagbo wi nipa ododo nigba ti o de ba won pe: “Ki ni eyi bi ko se idan ponnbele.”

Choose other languages: