Quran Apps in many lanuages:

Surah Saba Ayahs #18 Translated in Yoruba

فَلَمَّا قَضَيْنَا عَلَيْهِ الْمَوْتَ مَا دَلَّهُمْ عَلَىٰ مَوْتِهِ إِلَّا دَابَّةُ الْأَرْضِ تَأْكُلُ مِنْسَأَتَهُ ۖ فَلَمَّا خَرَّ تَبَيَّنَتِ الْجِنُّ أَنْ لَوْ كَانُوا يَعْلَمُونَ الْغَيْبَ مَا لَبِثُوا فِي الْعَذَابِ الْمُهِينِ
Nigba ti A pase pe ki iku pa (Anabi) Sulaemon, ko si ohun ti o mu awon alujannu mo pe o ti ku bi ko se kokoro inu ile kan ti o je opa re. Nigba ti o wo lule, o han kedere si awon alujannu pe ti o ba je pe awon ni imo ikoko ni, awon iba ti wa ninu (ise) iya t’o n yepere eda
لَقَدْ كَانَ لِسَبَإٍ فِي مَسْكَنِهِمْ آيَةٌ ۖ جَنَّتَانِ عَنْ يَمِينٍ وَشِمَالٍ ۖ كُلُوا مِنْ رِزْقِ رَبِّكُمْ وَاشْكُرُوا لَهُ ۚ بَلْدَةٌ طَيِّبَةٌ وَرَبٌّ غَفُورٌ
Dajudaju ami kan wa fun awon Saba’ ninu ibugbe won; (ohun ni) ogba oko meji t’o wa ni otun ati ni osi. “E je ninu arisiki Oluwa yin. Ki e si dupe fun Un.” Ilu t’o dara ni (ile Saba’. Allahu si ni) Oluwa Alaforijin
فَأَعْرَضُوا فَأَرْسَلْنَا عَلَيْهِمْ سَيْلَ الْعَرِمِ وَبَدَّلْنَاهُمْ بِجَنَّتَيْهِمْ جَنَّتَيْنِ ذَوَاتَيْ أُكُلٍ خَمْطٍ وَأَثْلٍ وَشَيْءٍ مِنْ سِدْرٍ قَلِيلٍ
Won gbunri (nibi esin). Nitori naa, A ran adagun odo ti won mo odi yika si won. A si paaro oko won mejeeji fun won pelu oko meji miiran ti o je oko eleso kikoro, oko igi elegun-un ati kini kan die ninu igi sidir
ذَٰلِكَ جَزَيْنَاهُمْ بِمَا كَفَرُوا ۖ وَهَلْ نُجَازِي إِلَّا الْكَفُورَ
Iyen ni A fi san won ni esan nitori pe won sai moore. Nje A maa san eni kan lesan iya bi ko se alaimoore
وَجَعَلْنَا بَيْنَهُمْ وَبَيْنَ الْقُرَى الَّتِي بَارَكْنَا فِيهَا قُرًى ظَاهِرَةً وَقَدَّرْنَا فِيهَا السَّيْرَ ۖ سِيرُوا فِيهَا لَيَالِيَ وَأَيَّامًا آمِنِينَ
A si fi awon ilu kan t’o han si aarin ilu ti A ran adagun odo si ati awon ilu ti A fi ibukun si. A si seto ibuso niwon-niwon fun irin-ajo sise sinu awon ilu naa. E rin lo sinu won ni oru ati ni oju ojo pelu ifayabale

Choose other languages: