Quran Apps in many lanuages:

Surah Muhammad Ayahs #29 Translated in Yoruba

إِنَّ الَّذِينَ ارْتَدُّوا عَلَىٰ أَدْبَارِهِمْ مِنْ بَعْدِ مَا تَبَيَّنَ لَهُمُ الْهُدَى ۙ الشَّيْطَانُ سَوَّلَ لَهُمْ وَأَمْلَىٰ لَهُمْ
Dajudaju awon t’o peyin da (si ’Islam) leyin ti imona ti foju han si won, Esu lo se isina ni oso fun won. O si fun won ni ireti asan nipa emi gigun
ذَٰلِكَ بِأَنَّهُمْ قَالُوا لِلَّذِينَ كَرِهُوا مَا نَزَّلَ اللَّهُ سَنُطِيعُكُمْ فِي بَعْضِ الْأَمْرِ ۖ وَاللَّهُ يَعْلَمُ إِسْرَارَهُمْ
Iyen nitori pe (awon alaisan okan) n so fun awon t’o korira ohun ti Allahu sokale pe: "Awa yoo tele yin ninu apa kan oro naa." Allahu si mo asiri won
فَكَيْفَ إِذَا تَوَفَّتْهُمُ الْمَلَائِكَةُ يَضْرِبُونَ وُجُوهَهُمْ وَأَدْبَارَهُمْ
Bawo ni (o se maa ri) nigba ti awon molaika ba gba emi won, ti won yo si maa gba oju won ati eyin won
ذَٰلِكَ بِأَنَّهُمُ اتَّبَعُوا مَا أَسْخَطَ اللَّهَ وَكَرِهُوا رِضْوَانَهُ فَأَحْبَطَ أَعْمَالَهُمْ
Iyen nitori pe dajudaju won tele ohun ti o bi Allahu ninu. Won si tun korira iyonu Re. Nitori naa, Allahu ti ba awon ise won je
أَمْ حَسِبَ الَّذِينَ فِي قُلُوبِهِمْ مَرَضٌ أَنْ لَنْ يُخْرِجَ اللَّهُ أَضْغَانَهُمْ
Tabi awon ti arun wa ninu okan won n lero pe Allahu ko nii se afihan adisokan buruku won ni

Choose other languages: