Quran Apps in many lanuages:

Surah Luqman Ayahs #29 Translated in Yoruba

وَلَئِنْ سَأَلْتَهُمْ مَنْ خَلَقَ السَّمَاوَاتِ وَالْأَرْضَ لَيَقُولُنَّ اللَّهُ ۚ قُلِ الْحَمْدُ لِلَّهِ ۚ بَلْ أَكْثَرُهُمْ لَا يَعْلَمُونَ
Dajudaju ti o ba bi won leere pe: “Ta ni O da awon sanmo ati ile?”, dajudaju won a wi pe: “Allahu ni.” So pe: “Gbogbo ope n je ti Allahu, sugbon opolopo won ko mo
لِلَّهِ مَا فِي السَّمَاوَاتِ وَالْأَرْضِ ۚ إِنَّ اللَّهَ هُوَ الْغَنِيُّ الْحَمِيدُ
Ti Allahu ni ohunkohun t’o wa ninu awon sanmo ati ile. Dajudaju Allahu, Oun ni Oloro, Olope
وَلَوْ أَنَّمَا فِي الْأَرْضِ مِنْ شَجَرَةٍ أَقْلَامٌ وَالْبَحْرُ يَمُدُّهُ مِنْ بَعْدِهِ سَبْعَةُ أَبْحُرٍ مَا نَفِدَتْ كَلِمَاتُ اللَّهِ ۗ إِنَّ اللَّهَ عَزِيزٌ حَكِيمٌ
Ti o ba je pe kikida ohun t’o n be lori ile ni igi ni gege ikowe, ki agbami odo je tadaa re, agbami odo meje (tun wa) leyin re (t’o maa kun un), awon oro Allahu ko nii tan (leyin ti awon nnkan ikowe wonyi ba tan nile). Dajudaju Allahu ni Alagbara, Ologbon
مَا خَلْقُكُمْ وَلَا بَعْثُكُمْ إِلَّا كَنَفْسٍ وَاحِدَةٍ ۗ إِنَّ اللَّهَ سَمِيعٌ بَصِيرٌ
Iseda yin ati ajinde yin ko tayo bi (iseda ati ajinde) emi eyo kan. Dajudaju Allahu ni Olugbo, Oluriran
أَلَمْ تَرَ أَنَّ اللَّهَ يُولِجُ اللَّيْلَ فِي النَّهَارِ وَيُولِجُ النَّهَارَ فِي اللَّيْلِ وَسَخَّرَ الشَّمْسَ وَالْقَمَرَ كُلٌّ يَجْرِي إِلَىٰ أَجَلٍ مُسَمًّى وَأَنَّ اللَّهَ بِمَا تَعْمَلُونَ خَبِيرٌ
Se o o ri i pe dajudaju Allahu l’O n ti oru bo inu osan, O n ti osan bo inu oru, O si ro oorun ati osupa? Ikookan won si n rin titi di gbedeke akoko kan. Ati pe (se o o ri i pe) dajudaju Allahu ni Alamotan nipa ohun ti e n se nise

Choose other languages: