Quran Apps in many lanuages:

Surah Luqman Ayahs #13 Translated in Yoruba

خَالِدِينَ فِيهَا ۖ وَعْدَ اللَّهِ حَقًّا ۚ وَهُوَ الْعَزِيزُ الْحَكِيمُ
Olusegbere ni won ninu re. (O je) adehun ti Allahu se ni ti ododo. Oun si ni Alagbara, Ologbon
خَلَقَ السَّمَاوَاتِ بِغَيْرِ عَمَدٍ تَرَوْنَهَا ۖ وَأَلْقَىٰ فِي الْأَرْضِ رَوَاسِيَ أَنْ تَمِيدَ بِكُمْ وَبَثَّ فِيهَا مِنْ كُلِّ دَابَّةٍ ۚ وَأَنْزَلْنَا مِنَ السَّمَاءِ مَاءً فَأَنْبَتْنَا فِيهَا مِنْ كُلِّ زَوْجٍ كَرِيمٍ
O da awon sanmo lai ni opo ti e le ri. O si ju awon apata t’o duro gbagidi sinu ile ki o ma fi le mi mo yin lese. O fon gbogbo nnkan abemi ka sori ile. A tun so omi kale lati sanmo, A si fi mu gbogbo orisirisi eso daadaa hu jade lati inu ile
هَٰذَا خَلْقُ اللَّهِ فَأَرُونِي مَاذَا خَلَقَ الَّذِينَ مِنْ دُونِهِ ۚ بَلِ الظَّالِمُونَ فِي ضَلَالٍ مُبِينٍ
Eyi ni eda ti Allahu. Nitori naa, e fi ohun ti awon miiran leyin Re da han mi! Rara o! Awon alabosi wa ninu isina ponnbele ni
وَلَقَدْ آتَيْنَا لُقْمَانَ الْحِكْمَةَ أَنِ اشْكُرْ لِلَّهِ ۚ وَمَنْ يَشْكُرْ فَإِنَّمَا يَشْكُرُ لِنَفْسِهِ ۖ وَمَنْ كَفَرَ فَإِنَّ اللَّهَ غَنِيٌّ حَمِيدٌ
Dajudaju A ti fun Luƙmon ni ogbon, pe: “Dupe fun Allahu.” Enikeni ti o ba dupe, o n dupe fun emi ara re ni. Enikeni ti o ba si sai moore, dajudaju Allahu ni Oloro, Olope (ti ope to si)
وَإِذْ قَالَ لُقْمَانُ لِابْنِهِ وَهُوَ يَعِظُهُ يَا بُنَيَّ لَا تُشْرِكْ بِاللَّهِ ۖ إِنَّ الشِّرْكَ لَظُلْمٌ عَظِيمٌ
(Ranti) nigba ti Luƙmon so fun omo re nigba ti o n se waasi fun un, pe: “Omo mi, ma se sebo si Allahu. Dajudaju ebo sise ni abosi nla

Choose other languages: