Quran Apps in many lanuages:

Surah Ibrahim Ayahs #42 Translated in Yoruba

رَبَّنَا إِنَّكَ تَعْلَمُ مَا نُخْفِي وَمَا نُعْلِنُ ۗ وَمَا يَخْفَىٰ عَلَى اللَّهِ مِنْ شَيْءٍ فِي الْأَرْضِ وَلَا فِي السَّمَاءِ
Oluwa wa, dajudaju Iwo l’O mo ohun ti a n fi pamo ati ohun ti a n se afihan re. Ko si si kini kan ninu ile ati ninu sanmo t’o pamo fun Allahu
الْحَمْدُ لِلَّهِ الَّذِي وَهَبَ لِي عَلَى الْكِبَرِ إِسْمَاعِيلَ وَإِسْحَاقَ ۚ إِنَّ رَبِّي لَسَمِيعُ الدُّعَاءِ
Gbogbo ope n je ti Allahu, Eni ti O fun mi ni ’Ismo‘il ati ’Ishaƙ nigba ti mo ti darugbo. Dajudaju, Oluwa mi ni Olugbo adua
رَبِّ اجْعَلْنِي مُقِيمَ الصَّلَاةِ وَمِنْ ذُرِّيَّتِي ۚ رَبَّنَا وَتَقَبَّلْ دُعَاءِ
Oluwa mi, se emi ati ninu aromodomo mi ni olukirun. Oluwa wa, ki O si gba adua mi
رَبَّنَا اغْفِرْ لِي وَلِوَالِدَيَّ وَلِلْمُؤْمِنِينَ يَوْمَ يَقُومُ الْحِسَابُ
Oluwa mi, saforijin fun emi ati awon obi mi mejeeji ati awon onigbagbo ododo ni ojo ti isiro-ise yoo sele
وَلَا تَحْسَبَنَّ اللَّهَ غَافِلًا عَمَّا يَعْمَلُ الظَّالِمُونَ ۚ إِنَّمَا يُؤَخِّرُهُمْ لِيَوْمٍ تَشْخَصُ فِيهِ الْأَبْصَارُ
Ma se lero pe Allahu gbagbe nnkan ti awon alabosi n se nise. O kan n lo won lara di ojo kan ti awon oju yoo yo sita rangandan

Choose other languages: