Quran Apps in many lanuages:

Surah Ibrahim Ayahs #22 Translated in Yoruba

مَثَلُ الَّذِينَ كَفَرُوا بِرَبِّهِمْ ۖ أَعْمَالُهُمْ كَرَمَادٍ اشْتَدَّتْ بِهِ الرِّيحُ فِي يَوْمٍ عَاصِفٍ ۖ لَا يَقْدِرُونَ مِمَّا كَسَبُوا عَلَىٰ شَيْءٍ ۚ ذَٰلِكَ هُوَ الضَّلَالُ الْبَعِيدُ
Afiwe awon t’o sai gbagbo ninu Oluwa won: awon ise won da bi eeru ti ategun fe danu patapata ni ojo iji ategun. Won ko ni agbara kan lori ohun ti won se nise. Iyen ni isina t’o jinna
أَلَمْ تَرَ أَنَّ اللَّهَ خَلَقَ السَّمَاوَاتِ وَالْأَرْضَ بِالْحَقِّ ۚ إِنْ يَشَأْ يُذْهِبْكُمْ وَيَأْتِ بِخَلْقٍ جَدِيدٍ
Se o o ri i pe dajudaju Allahu l’O seda awon sanmo ati ile pelu ododo? Ti O ba fe, O maa ko yin kuro. O si maa mu eda titun wa
وَمَا ذَٰلِكَ عَلَى اللَّهِ بِعَزِيزٍ
Iyen ko si le da Allahu lagara
وَبَرَزُوا لِلَّهِ جَمِيعًا فَقَالَ الضُّعَفَاءُ لِلَّذِينَ اسْتَكْبَرُوا إِنَّا كُنَّا لَكُمْ تَبَعًا فَهَلْ أَنْتُمْ مُغْنُونَ عَنَّا مِنْ عَذَابِ اللَّهِ مِنْ شَيْءٍ ۚ قَالُوا لَوْ هَدَانَا اللَّهُ لَهَدَيْنَاكُمْ ۖ سَوَاءٌ عَلَيْنَا أَجَزِعْنَا أَمْ صَبَرْنَا مَا لَنَا مِنْ مَحِيصٍ
Gbogbo eda si maa jade sodo Allahu (lojo Ajinde). Nigba naa, awon alailagbara yoo wi fun awon t’o segberaga pe: “Dajudaju awa je omoleyin fun yin, nje eyin le gbe nnkan kan kuro fun wa ninu iya Allahu?” Won yoo wi pe: “Ti o ba je pe Allahu to wa sona ni, awa iba to yin sona. Bakan naa si ni fun wa, yala a kaya soke tabi a satemora (iya); ko si ibusasi kan fun wa.”
وَقَالَ الشَّيْطَانُ لَمَّا قُضِيَ الْأَمْرُ إِنَّ اللَّهَ وَعَدَكُمْ وَعْدَ الْحَقِّ وَوَعَدْتُكُمْ فَأَخْلَفْتُكُمْ ۖ وَمَا كَانَ لِيَ عَلَيْكُمْ مِنْ سُلْطَانٍ إِلَّا أَنْ دَعَوْتُكُمْ فَاسْتَجَبْتُمْ لِي ۖ فَلَا تَلُومُونِي وَلُومُوا أَنْفُسَكُمْ ۖ مَا أَنَا بِمُصْرِخِكُمْ وَمَا أَنْتُمْ بِمُصْرِخِيَّ ۖ إِنِّي كَفَرْتُ بِمَا أَشْرَكْتُمُونِ مِنْ قَبْلُ ۗ إِنَّ الظَّالِمِينَ لَهُمْ عَذَابٌ أَلِيمٌ
Esu yo si wi nigba ti A ba sedajo (eda) tan, pe: “Dajudaju Allahu se adehun fun yin ni adehun ododo. Emi naa se adehun fun yin. Mo si yapa adehun ti mo se fun yin. Emi ko si ni agbara kan lori yin bi ko se pe mo pe yin e si jepe mi. Nitori naa, e ma se bu mi; ara yin ni ki e bu. Emi ko le ran yin lowo (nibi iya), Eyin naa ko si le ran mi lowo (nibi iya). Dajudaju emi ti lodi si ohun ti e fi so mi di akegbe Allahu siwaju.” Dajudaju awon alabosi, iya eleta-elero wa fun won

Choose other languages: