Quran Apps in many lanuages:

Surah Hud Ayahs #38 Translated in Yoruba

وَلَا يَنْفَعُكُمْ نُصْحِي إِنْ أَرَدْتُ أَنْ أَنْصَحَ لَكُمْ إِنْ كَانَ اللَّهُ يُرِيدُ أَنْ يُغْوِيَكُمْ ۚ هُوَ رَبُّكُمْ وَإِلَيْهِ تُرْجَعُونَ
Imoran mi ko si le se yin ni anfaani ti mo ba fe gba yin nimoran, ti Allahu ba fe pa yin run. Oun ni Oluwa yin. Odo Re si ni won yoo da yin pada si
أَمْ يَقُولُونَ افْتَرَاهُ ۖ قُلْ إِنِ افْتَرَيْتُهُ فَعَلَيَّ إِجْرَامِي وَأَنَا بَرِيءٌ مِمَّا تُجْرِمُونَ
Tabi won n wi pe: "O hun un ni." So pe: "Ti mo ba hun un, emi ni mo ni ese mi. Emi si yowo yose ninu ohun ti e n da lese
وَأُوحِيَ إِلَىٰ نُوحٍ أَنَّهُ لَنْ يُؤْمِنَ مِنْ قَوْمِكَ إِلَّا مَنْ قَدْ آمَنَ فَلَا تَبْتَئِسْ بِمَا كَانُوا يَفْعَلُونَ
A si fi imisi ranse si (Anabi) Nuh pe dajudaju ko si eni kan ti o maa gbagbo mo ninu ijo re afi eni t’o ti gbagbo tele. Nitori naa, ma se banuje nipa nnkan ti won n se nise
وَاصْنَعِ الْفُلْكَ بِأَعْيُنِنَا وَوَحْيِنَا وَلَا تُخَاطِبْنِي فِي الَّذِينَ ظَلَمُوا ۚ إِنَّهُمْ مُغْرَقُونَ
Ki o si kan oko oju-omi naa loju Wa (bayii) pelu imisi Wa. Ma si se ba Mi soro nipa awon t’o sabosi. Dajudaju A maa te won ri ni
وَيَصْنَعُ الْفُلْكَ وَكُلَّمَا مَرَّ عَلَيْهِ مَلَأٌ مِنْ قَوْمِهِ سَخِرُوا مِنْهُ ۚ قَالَ إِنْ تَسْخَرُوا مِنَّا فَإِنَّا نَسْخَرُ مِنْكُمْ كَمَا تَسْخَرُونَ
O si n kan oko oju-omi naa lo. Nigbakigba ti awon otokulu ninu ijo re ba koja lodo re, won yo si maa fi se yeye. (Anabi Nuh) si so pe: "Ti e ba fi wa se yeye, dajudaju awa naa yoo fi yin se yeye gege bi e se n fi wa se yeye

Choose other languages: