Quran Apps in many lanuages:

Surah Hud Ayahs #15 Translated in Yoruba

إِلَّا الَّذِينَ صَبَرُوا وَعَمِلُوا الصَّالِحَاتِ أُولَٰئِكَ لَهُمْ مَغْفِرَةٌ وَأَجْرٌ كَبِيرٌ
Ayafi awon t’o ba se suuru, ti won si se awon ise rere. Awon wonyen, ti won ni aforijin ati esan t’o tobi
فَلَعَلَّكَ تَارِكٌ بَعْضَ مَا يُوحَىٰ إِلَيْكَ وَضَائِقٌ بِهِ صَدْرُكَ أَنْ يَقُولُوا لَوْلَا أُنْزِلَ عَلَيْهِ كَنْزٌ أَوْ جَاءَ مَعَهُ مَلَكٌ ۚ إِنَّمَا أَنْتَ نَذِيرٌ ۚ وَاللَّهُ عَلَىٰ كُلِّ شَيْءٍ وَكِيلٌ
Boya o fe gbe apa kan ohun ti A fi ranse si o sile, ki irewesi si ba okan re nipa re (ni ti ipaya pe) won n wi pe: "Ki ni ko je ki apoti-oro kan sokale fun un, tabi ki molaika kan ba a wa?” Olukilo ni iwo. Allahu si ni Oluso lori gbogbo nnkan
أَمْ يَقُولُونَ افْتَرَاهُ ۖ قُلْ فَأْتُوا بِعَشْرِ سُوَرٍ مِثْلِهِ مُفْتَرَيَاتٍ وَادْعُوا مَنِ اسْتَطَعْتُمْ مِنْ دُونِ اللَّهِ إِنْ كُنْتُمْ صَادِقِينَ
Tabi won n wi pe: “O hun un ni.” So pe: “E mu surah mewaa adahun bi iru re wa, ki e si ke si eni ti e ba le ke si leyin Allahu ti e ba je olododo.”
فَإِلَّمْ يَسْتَجِيبُوا لَكُمْ فَاعْلَمُوا أَنَّمَا أُنْزِلَ بِعِلْمِ اللَّهِ وَأَنْ لَا إِلَٰهَ إِلَّا هُوَ ۖ فَهَلْ أَنْتُمْ مُسْلِمُونَ
Nigba naa ti won ko ba da yin lohun, ki e mo pe dajudaju won so (al-Ƙur’an) kale pelu imo Allahu. Ati pe ko si olohun ti ijosin to si afi Oun. Nitori naa, se eyin yoo di musulumi
مَنْ كَانَ يُرِيدُ الْحَيَاةَ الدُّنْيَا وَزِينَتَهَا نُوَفِّ إِلَيْهِمْ أَعْمَالَهُمْ فِيهَا وَهُمْ فِيهَا لَا يُبْخَسُونَ
Enikeni ti o ba n fe isemi aye ati oso re, A oo san won ni esan ise won nile aye. A o si nii din kini kan ku fun won nile aye

Choose other languages: