Quran Apps in many lanuages:

Surah Ghafir Ayahs #29 Translated in Yoruba

فَلَمَّا جَاءَهُمْ بِالْحَقِّ مِنْ عِنْدِنَا قَالُوا اقْتُلُوا أَبْنَاءَ الَّذِينَ آمَنُوا مَعَهُ وَاسْتَحْيُوا نِسَاءَهُمْ ۚ وَمَا كَيْدُ الْكَافِرِينَ إِلَّا فِي ضَلَالٍ
Nigba ti o mu ododo naa de odo won lati odo Wa, won wi pe: "E pa awon omokunrin awon t’o gbagbo pelu re, ki e si fi awon omobinrin won sile." Ete awon alaigbagbo ko si ninu kini kan bi ko se ninu ofo
وَقَالَ فِرْعَوْنُ ذَرُونِي أَقْتُلْ مُوسَىٰ وَلْيَدْعُ رَبَّهُ ۖ إِنِّي أَخَافُ أَنْ يُبَدِّلَ دِينَكُمْ أَوْ أَنْ يُظْهِرَ فِي الْأَرْضِ الْفَسَادَ
Fir‘aon wi pe: "E fi mi sile ki ng pa Musa, ki o si pe Oluwa re (wo boya O maa gba a sile). Dajudaju emi n beru pe o maa yi esin yin pada tabi pe o maa safi han ibaje lori ile
وَقَالَ مُوسَىٰ إِنِّي عُذْتُ بِرَبِّي وَرَبِّكُمْ مِنْ كُلِّ مُتَكَبِّرٍ لَا يُؤْمِنُ بِيَوْمِ الْحِسَابِ
(Anabi) Musa so pe: "Dajudaju emi sa di Oluwa mi ati Oluwa yin kuro lowo gbogbo onigbeeraga, ti ko gba Ojo isiro-ise gbo
وَقَالَ رَجُلٌ مُؤْمِنٌ مِنْ آلِ فِرْعَوْنَ يَكْتُمُ إِيمَانَهُ أَتَقْتُلُونَ رَجُلًا أَنْ يَقُولَ رَبِّيَ اللَّهُ وَقَدْ جَاءَكُمْ بِالْبَيِّنَاتِ مِنْ رَبِّكُمْ ۖ وَإِنْ يَكُ كَاذِبًا فَعَلَيْهِ كَذِبُهُ ۖ وَإِنْ يَكُ صَادِقًا يُصِبْكُمْ بَعْضُ الَّذِي يَعِدُكُمْ ۖ إِنَّ اللَّهَ لَا يَهْدِي مَنْ هُوَ مُسْرِفٌ كَذَّابٌ
Okunrin onigbagbo ododo kan t’o n fi igbagbo re pamo ninu awon eniyan Fir‘aon so pe: "Se e maa pa okunrin kan nitori pe o n so pe, ‘Allahu ni Oluwa mi.’ O si kuku ti mu awon eri t’o yanju wa ba yin lati odo Oluwa yin. Ti o ba je opuro, (iya) iro re wa lori re. Ti o ba si je olododo, apa kan eyi ti o se ni ileri fun yin yo si ko le yin lori. Dajudaju Allahu ko nii fi ona mo eni ti o je alaseju, opuro
يَا قَوْمِ لَكُمُ الْمُلْكُ الْيَوْمَ ظَاهِرِينَ فِي الْأَرْضِ فَمَنْ يَنْصُرُنَا مِنْ بَأْسِ اللَّهِ إِنْ جَاءَنَا ۚ قَالَ فِرْعَوْنُ مَا أُرِيكُمْ إِلَّا مَا أَرَىٰ وَمَا أَهْدِيكُمْ إِلَّا سَبِيلَ الرَّشَادِ
Eyin eniyan mi, eyin l’e ni ijoba lonii, eyin si ni alase lori ile naa. Sugbon ta ni o maa ran wa lowo ti iya Allahu ba de ba wa?" Fir‘aon wi pe: "Emi ko fi nnkan kan han yin bi ko se ohun ti mo ri (ninu oye mi). Emi ko si to yin si ona kan bi ko se oju ona imona

Choose other languages: