Quran Apps in many lanuages:

Surah Fussilat Ayahs #50 Translated in Yoruba

مَنْ عَمِلَ صَالِحًا فَلِنَفْسِهِ ۖ وَمَنْ أَسَاءَ فَعَلَيْهَا ۗ وَمَا رَبُّكَ بِظَلَّامٍ لِلْعَبِيدِ
Enikeni ti o ba se ise rere, o se e fun emi ara re. Enikeni ti o ba si se aburu, o se e fun emi ara re. Oluwa re ko si nii se abosi si awon erusin
إِلَيْهِ يُرَدُّ عِلْمُ السَّاعَةِ ۚ وَمَا تَخْرُجُ مِنْ ثَمَرَاتٍ مِنْ أَكْمَامِهَا وَمَا تَحْمِلُ مِنْ أُنْثَىٰ وَلَا تَضَعُ إِلَّا بِعِلْمِهِ ۚ وَيَوْمَ يُنَادِيهِمْ أَيْنَ شُرَكَائِي قَالُوا آذَنَّاكَ مَا مِنَّا مِنْ شَهِيدٍ
Odo Re ni won yoo maa da imo Akoko naa pada si. Ko si eso kan ti o maa jade ninu apo re, obinrin kan ko si nii loyun, ko si nii bimo afi pelu imo Re. (Ranti) ojo ti O si maa pe won pe: "Ibo ni awon akegbe Mi (ti e josin fun) wa?" Won a wi pe: "Awa n je ki O mo pe ko si olujerii kan ninu wa (ti o maa jerii pe O ni akegbe)
وَضَلَّ عَنْهُمْ مَا كَانُوا يَدْعُونَ مِنْ قَبْلُ ۖ وَظَنُّوا مَا لَهُمْ مِنْ مَحِيصٍ
Ohun ti won n pe teletele si dofo mo won lowo. Won si mo ni amodaju pe ko si ibusasi kan fun awon
لَا يَسْأَمُ الْإِنْسَانُ مِنْ دُعَاءِ الْخَيْرِ وَإِنْ مَسَّهُ الشَّرُّ فَيَئُوسٌ قَنُوطٌ
Eniyan ko ko susu nibi adua (lati toro) oore. Ti aburu ba si fowo ba a, o maa di olusoretinu, olujakanmuna
وَلَئِنْ أَذَقْنَاهُ رَحْمَةً مِنَّا مِنْ بَعْدِ ضَرَّاءَ مَسَّتْهُ لَيَقُولَنَّ هَٰذَا لِي وَمَا أَظُنُّ السَّاعَةَ قَائِمَةً وَلَئِنْ رُجِعْتُ إِلَىٰ رَبِّي إِنَّ لِي عِنْدَهُ لَلْحُسْنَىٰ ۚ فَلَنُنَبِّئَنَّ الَّذِينَ كَفَرُوا بِمَا عَمِلُوا وَلَنُذِيقَنَّهُمْ مِنْ عَذَابٍ غَلِيظٍ
Dajudaju ti A ba se idera fun un lati odo Wa leyin aburu ti o fowo ba a, dajudaju o maa wi pe: "Eyi ni temi. Emi ko si ni amodaju pe Akoko naa maa sele. Ati pe dajudaju ti Won ba da mi pada si odo Oluwa mi, dajudaju rere tun wa fun mi ni odo Re." Dajudaju Awa yoo fun awon t’o sai gbagbo ni iro ohun ti won se nise. Dajudaju A si maa fun won ni iya t’o nipon to wo

Choose other languages: