Quran Apps in many lanuages:

Surah Fatir Ayahs #16 Translated in Yoruba

وَمَا يَسْتَوِي الْبَحْرَانِ هَٰذَا عَذْبٌ فُرَاتٌ سَائِغٌ شَرَابُهُ وَهَٰذَا مِلْحٌ أُجَاجٌ ۖ وَمِنْ كُلٍّ تَأْكُلُونَ لَحْمًا طَرِيًّا وَتَسْتَخْرِجُونَ حِلْيَةً تَلْبَسُونَهَا ۖ وَتَرَى الْفُلْكَ فِيهِ مَوَاخِرَ لِتَبْتَغُوا مِنْ فَضْلِهِ وَلَعَلَّكُمْ تَشْكُرُونَ
Awon odo meji naa ko dogba; eyi ni (omi) didun gan-an, ti mimu re n lo tinrin lofun. Eyi si ni (omi) iyo t’o moro. Ati pe ninu gbogbo (omi odo wonyi) l’e ti n je eran (eja) tutu. E si n wa kusa awon ohun oso ti e n wo (sara). O si n ri awon oko oju-omi t’o n la aarin omi koja nitori ki e le wa ninu oore Allahu ati nitori ki e le dupe (fun Un)
يُولِجُ اللَّيْلَ فِي النَّهَارِ وَيُولِجُ النَّهَارَ فِي اللَّيْلِ وَسَخَّرَ الشَّمْسَ وَالْقَمَرَ كُلٌّ يَجْرِي لِأَجَلٍ مُسَمًّى ۚ ذَٰلِكُمُ اللَّهُ رَبُّكُمْ لَهُ الْمُلْكُ ۚ وَالَّذِينَ تَدْعُونَ مِنْ دُونِهِ مَا يَمْلِكُونَ مِنْ قِطْمِيرٍ
(Allahu) n ti oru bo inu osan. O si n ti osan bo inu oru. O ro oorun ati osupa; ikookan won n rin fun gbedeke akoko kan. Iyen ni Allahu, Oluwa yin. TiRe ni ijoba. Awon ti e si n pe leyin Re, won ko ni ikapa kan lori epo koro inu dabinu
إِنْ تَدْعُوهُمْ لَا يَسْمَعُوا دُعَاءَكُمْ وَلَوْ سَمِعُوا مَا اسْتَجَابُوا لَكُمْ ۖ وَيَوْمَ الْقِيَامَةِ يَكْفُرُونَ بِشِرْكِكُمْ ۚ وَلَا يُنَبِّئُكَ مِثْلُ خَبِيرٍ
Ti e ba pe won, won ko le gbo ipe yin. Ti o ba si je pe won gbo, won ko le da yin lohun. Ati pe ni Ojo Ajinde, won yoo tako bi e se fi won se akegbe fun Allahu. Ko si si eni ti o le fun o ni iro kan (nipa eda ju) iru (iro ti) Onimo-ikoko (fun o nipa won)
يَا أَيُّهَا النَّاسُ أَنْتُمُ الْفُقَرَاءُ إِلَى اللَّهِ ۖ وَاللَّهُ هُوَ الْغَنِيُّ الْحَمِيدُ
Eyin eniyan, eyin ni alaini (ti e ni bukata) si Allahu. Allahu, Oun ni Oloro, Olope
إِنْ يَشَأْ يُذْهِبْكُمْ وَيَأْتِ بِخَلْقٍ جَدِيدٍ
Ti O ba fe, O maa ko yin kuro nile. O si maa mu eda titun wa

Choose other languages: