Quran Apps in many lanuages:

Surah Az-Zamar Ayahs #29 Translated in Yoruba

كَذَّبَ الَّذِينَ مِنْ قَبْلِهِمْ فَأَتَاهُمُ الْعَذَابُ مِنْ حَيْثُ لَا يَشْعُرُونَ
Awon t’o siwaju won pe ododo niro. Nitori naa, iya de ba won ni aye ti won ko ti fura
فَأَذَاقَهُمُ اللَّهُ الْخِزْيَ فِي الْحَيَاةِ الدُّنْيَا ۖ وَلَعَذَابُ الْآخِرَةِ أَكْبَرُ ۚ لَوْ كَانُوا يَعْلَمُونَ
Allahu fun won ni abuku iya to wo ninu isemi aye yii. Iya orun si tobi julo ti o ba je pe won mo
وَلَقَدْ ضَرَبْنَا لِلنَّاسِ فِي هَٰذَا الْقُرْآنِ مِنْ كُلِّ مَثَلٍ لَعَلَّهُمْ يَتَذَكَّرُونَ
A si ti se gbogbo akawe fun awon eniyan ninu al-Ƙur’an yii nitori ki won le lo iranti
قُرْآنًا عَرَبِيًّا غَيْرَ ذِي عِوَجٍ لَعَلَّهُمْ يَتَّقُونَ
Al-Ƙur’an ni ede Larubawa, eyi ti oro inu re ko doju ru (l’A sokale) nitori ki won le beru (Allahu)
ضَرَبَ اللَّهُ مَثَلًا رَجُلًا فِيهِ شُرَكَاءُ مُتَشَاكِسُونَ وَرَجُلًا سَلَمًا لِرَجُلٍ هَلْ يَسْتَوِيَانِ مَثَلًا ۚ الْحَمْدُ لِلَّهِ ۚ بَلْ أَكْثَرُهُمْ لَا يَعْلَمُونَ
Allahu fi akawe kan lele; erukunrin kan t’o wa labe ase oga pupo ti won n fa a kiri (ko si mo ta ni o maa da lohun ninu awon oga re) ati (akawe) erukunrin kan t’o da wa gedegbe labe ogakunrin kan. Nje awon (eru) mejeeji dogba ni akawe bi? Gbogbo ope n je ti Allahu, sugbon opolopo won ni ko mo

Choose other languages: