Quran Apps in many lanuages:

Surah At-Tawba Ayahs #102 Translated in Yoruba

وَمِنَ الْأَعْرَابِ مَنْ يَتَّخِذُ مَا يُنْفِقُ مَغْرَمًا وَيَتَرَبَّصُ بِكُمُ الدَّوَائِرَ ۚ عَلَيْهِمْ دَائِرَةُ السَّوْءِ ۗ وَاللَّهُ سَمِيعٌ عَلِيمٌ
Ati pe o wa ninu awon Larubawa oko eni ti o ka inawo t’o n na (fun esin) si owo oran. O si n reti apadasi aburu fun yin. Awon si ni apadasi aburu yoo de ba. Allahu si ni Olugbo, Onimo
وَمِنَ الْأَعْرَابِ مَنْ يُؤْمِنُ بِاللَّهِ وَالْيَوْمِ الْآخِرِ وَيَتَّخِذُ مَا يُنْفِقُ قُرُبَاتٍ عِنْدَ اللَّهِ وَصَلَوَاتِ الرَّسُولِ ۚ أَلَا إِنَّهَا قُرْبَةٌ لَهُمْ ۚ سَيُدْخِلُهُمُ اللَّهُ فِي رَحْمَتِهِ ۗ إِنَّ اللَّهَ غَفُورٌ رَحِيمٌ
O tun wa ninu awon Larubawa oko, eni ti o gbagbo ninu Allahu ati Ojo Ikeyin, ti o si so inawo t’o n na (fun esin) di awon isunmo Allahu ati (gbigba) adua (lodo) Ojise. Kiye si i, dajudaju ohun ni isunmo Allahu fun won. Allahu yo si fi won sinu ike Re. Dajudaju Allahu ni Alaforijin, Asake-orun
وَالسَّابِقُونَ الْأَوَّلُونَ مِنَ الْمُهَاجِرِينَ وَالْأَنْصَارِ وَالَّذِينَ اتَّبَعُوهُمْ بِإِحْسَانٍ رَضِيَ اللَّهُ عَنْهُمْ وَرَضُوا عَنْهُ وَأَعَدَّ لَهُمْ جَنَّاتٍ تَجْرِي تَحْتَهَا الْأَنْهَارُ خَالِدِينَ فِيهَا أَبَدًا ۚ ذَٰلِكَ الْفَوْزُ الْعَظِيمُ
Awon asiwaju, awon eni akoko ninu awon Muhajirun ati awon ’Ansor pelu awon t’o fi daadaa tele won, Allahu yonu si won. Won si yonu si (ohun ti Allahu fun won). O tun pa lese sile de won awon Ogba Idera ti odo n san ni isale re. Olusegbere ni won ninu re titi laelae. Iyen ni erenje nla
وَمِمَّنْ حَوْلَكُمْ مِنَ الْأَعْرَابِ مُنَافِقُونَ ۖ وَمِنْ أَهْلِ الْمَدِينَةِ ۖ مَرَدُوا عَلَى النِّفَاقِ لَا تَعْلَمُهُمْ ۖ نَحْنُ نَعْلَمُهُمْ ۚ سَنُعَذِّبُهُمْ مَرَّتَيْنِ ثُمَّ يُرَدُّونَ إِلَىٰ عَذَابٍ عَظِيمٍ
Awon sobe-selu musulumi kan n be ninu awon ti o wa ni ayika yin ninu awon Larubawa oko ati ninu awon ara ilu Modinah, ti won wonkoko mo isobe-selu. O o mo won, Awa l’A mo won. A oo je won niya ni ee meji. Leyin naa, A oo da won pada sinu iya nla
وَآخَرُونَ اعْتَرَفُوا بِذُنُوبِهِمْ خَلَطُوا عَمَلًا صَالِحًا وَآخَرَ سَيِّئًا عَسَى اللَّهُ أَنْ يَتُوبَ عَلَيْهِمْ ۚ إِنَّ اللَّهَ غَفُورٌ رَحِيمٌ
Awon miiran jewo ese won. Won da ise rere po mo ise miiran t’o buru. Boya Allahu yoo gba ironupiwada won. Dajudaju Allahu ni Alaforijin, Asake-orun

Choose other languages: