Quran Apps in many lanuages:

Surah At-Tawba Ayahs #86 Translated in Yoruba

فَلْيَضْحَكُوا قَلِيلًا وَلْيَبْكُوا كَثِيرًا جَزَاءً بِمَا كَانُوا يَكْسِبُونَ
Nitori naa, ki won rerin-in die, ki won si sunkun pupo; (o je) esan (fun) ohun ti won n se nise
فَإِنْ رَجَعَكَ اللَّهُ إِلَىٰ طَائِفَةٍ مِنْهُمْ فَاسْتَأْذَنُوكَ لِلْخُرُوجِ فَقُلْ لَنْ تَخْرُجُوا مَعِيَ أَبَدًا وَلَنْ تُقَاتِلُوا مَعِيَ عَدُوًّا ۖ إِنَّكُمْ رَضِيتُمْ بِالْقُعُودِ أَوَّلَ مَرَّةٍ فَاقْعُدُوا مَعَ الْخَالِفِينَ
Ti Allahu ba mu o dele ba igun kan ninu won, ti won ba wa n gbase lodo re fun jijade fun ogun esin, so nigba naa pe: “Eyin ko le jade fun ogun esin mo pelu mi. Eyin ko si le ja ota kan logun mo pelu mi, nitori pe e ti yonu si ijokoo sile ni igba akoko. Nitori naa, e jokoo sile ti awon olusaseyin fun ogun esin.”
وَلَا تُصَلِّ عَلَىٰ أَحَدٍ مِنْهُمْ مَاتَ أَبَدًا وَلَا تَقُمْ عَلَىٰ قَبْرِهِ ۖ إِنَّهُمْ كَفَرُوا بِاللَّهِ وَرَسُولِهِ وَمَاتُوا وَهُمْ فَاسِقُونَ
Laelae, o o gbodo kirun si eni kan kan lara ninu won, ti o ba ku, o o si gbodo duro nibi saree re, nitori pe won sai gbagbo ninu Allahu ati Ojise Re. Won si ku nigba ti won wa nipo obileje
وَلَا تُعْجِبْكَ أَمْوَالُهُمْ وَأَوْلَادُهُمْ ۚ إِنَّمَا يُرِيدُ اللَّهُ أَنْ يُعَذِّبَهُمْ بِهَا فِي الدُّنْيَا وَتَزْهَقَ أَنْفُسُهُمْ وَهُمْ كَافِرُونَ
Ma se je ki awon dukia won ati awon omo won ya o lenu; Allahu kan fe fi je won niya ninu isemi aye (yii) ni. (O si fe ki) emi bo lara won, nigba ti won ba wa nipo alaigbagbo
وَإِذَا أُنْزِلَتْ سُورَةٌ أَنْ آمِنُوا بِاللَّهِ وَجَاهِدُوا مَعَ رَسُولِهِ اسْتَأْذَنَكَ أُولُو الطَّوْلِ مِنْهُمْ وَقَالُوا ذَرْنَا نَكُنْ مَعَ الْقَاعِدِينَ
Nigba ti A ba so surah kan kale pe ki won gbagbo ninu Allahu, ki won si jagun pelu Ojise Re, (nigba naa ni) awon oloro ninu won yoo maa toro iyonda lodo re, won a si wi pe: “Fi wa sile ki a wa pelu awon olujokoo sile.”

Choose other languages: