Quran Apps in many lanuages:

Surah Ash-Shura Ayahs #49 Translated in Yoruba

وَتَرَاهُمْ يُعْرَضُونَ عَلَيْهَا خَاشِعِينَ مِنَ الذُّلِّ يَنْظُرُونَ مِنْ طَرْفٍ خَفِيٍّ ۗ وَقَالَ الَّذِينَ آمَنُوا إِنَّ الْخَاسِرِينَ الَّذِينَ خَسِرُوا أَنْفُسَهُمْ وَأَهْلِيهِمْ يَوْمَ الْقِيَامَةِ ۗ أَلَا إِنَّ الظَّالِمِينَ فِي عَذَابٍ مُقِيمٍ
O si maa ri won ti A maa ko won lo sinu Ina; won yoo palolo lati ara iyepere, won yo si maa wo fin-in-fin. Awon t’o gbagbo ni ododo si maa so pe: "Dajudaju awon eni ofo ni awon t’o se emi ara won ati ara ile won ni ofo ni Ojo Ajinde." Kiye si i, dajudaju awon alabosi yoo wa ninu iya gbere
وَمَا كَانَ لَهُمْ مِنْ أَوْلِيَاءَ يَنْصُرُونَهُمْ مِنْ دُونِ اللَّهِ ۗ وَمَنْ يُضْلِلِ اللَّهُ فَمَا لَهُ مِنْ سَبِيلٍ
Ko si nii si alaabo kan fun won ti o maa ran won lowo leyin Allahu. Ati pe enikeni ti Allahu ba si lona, ko le si ona kan kan fun un
اسْتَجِيبُوا لِرَبِّكُمْ مِنْ قَبْلِ أَنْ يَأْتِيَ يَوْمٌ لَا مَرَدَّ لَهُ مِنَ اللَّهِ ۚ مَا لَكُمْ مِنْ مَلْجَإٍ يَوْمَئِذٍ وَمَا لَكُمْ مِنْ نَكِيرٍ
E jepe Oluwa yin siwaju ki ojo kan to de, ti ko si idapada kan fun un ni odo Allahu. Ko si ibusasi kan fun yin ni ojo yen. Ko si nii si olukoya kan fun yin
فَإِنْ أَعْرَضُوا فَمَا أَرْسَلْنَاكَ عَلَيْهِمْ حَفِيظًا ۖ إِنْ عَلَيْكَ إِلَّا الْبَلَاغُ ۗ وَإِنَّا إِذَا أَذَقْنَا الْإِنْسَانَ مِنَّا رَحْمَةً فَرِحَ بِهَا ۖ وَإِنْ تُصِبْهُمْ سَيِّئَةٌ بِمَا قَدَّمَتْ أَيْدِيهِمْ فَإِنَّ الْإِنْسَانَ كَفُورٌ
Nitori naa, ti won ba gbunri, A o ran o pe ki o je oluso fun won. Ko si kini kan t’o di dandan fun o bi ko se ise-jije. Ati pe dajudaju nigba ti A ba fun eniyan ni ike kan to wo lati odo Wa, o maa dunnu si i. Ti aburu kan ba si kan an nipase ohun ti owo won ti siwaju (ni ise aburu), dajudaju eniyan ni alaimoore
لِلَّهِ مُلْكُ السَّمَاوَاتِ وَالْأَرْضِ ۚ يَخْلُقُ مَا يَشَاءُ ۚ يَهَبُ لِمَنْ يَشَاءُ إِنَاثًا وَيَهَبُ لِمَنْ يَشَاءُ الذُّكُورَ
Ti Allahu ni ijoba awon sanmo ati ile. O n seda ohun ti O ba fe. O n ta eni ti O ba fe lore omobinrin. O si n ta eni ti O ba fe ni lore omokunrin

Choose other languages: