Quran Apps in many lanuages:

Surah Ash-Shura Ayahs #40 Translated in Yoruba

فَمَا أُوتِيتُمْ مِنْ شَيْءٍ فَمَتَاعُ الْحَيَاةِ الدُّنْيَا ۖ وَمَا عِنْدَ اللَّهِ خَيْرٌ وَأَبْقَىٰ لِلَّذِينَ آمَنُوا وَعَلَىٰ رَبِّهِمْ يَتَوَكَّلُونَ
Nitori naa, ohunkohun ti A ba fun yin, igbadun aye nikan ni. Ohun ti o wa lodo Allahu loore julo, o si maa seku titi laelae fun awon t’o gbagbo ni ododo, ti won si n gbarale Oluwa won
وَالَّذِينَ يَجْتَنِبُونَ كَبَائِرَ الْإِثْمِ وَالْفَوَاحِشَ وَإِذَا مَا غَضِبُوا هُمْ يَغْفِرُونَ
(Ohun ti o wa lodo Allahu tun wa fun) awon t’o n jinna si awon ese nlanla ati awon iwa ibaje, ati (awon t’o je pe) nigba ti won ba binu, won yoo saforijin
وَالَّذِينَ اسْتَجَابُوا لِرَبِّهِمْ وَأَقَامُوا الصَّلَاةَ وَأَمْرُهُمْ شُورَىٰ بَيْنَهُمْ وَمِمَّا رَزَقْنَاهُمْ يُنْفِقُونَ
(Ohun ti o wa lodo Allahu tun wa fun) awon t’o jepe ti Oluwa won, ti won n kirun, oro ara won si je ijiroro laaarin ara won, won tun n na ninu arisiki ti A pese fun won
وَالَّذِينَ إِذَا أَصَابَهُمُ الْبَغْيُ هُمْ يَنْتَصِرُونَ
(Ohun ti o wa lodo Allahu tun wa fun) awon ti (o je pe) nigba ti won ba se abosi si won, won yoo gbesan won pada
وَجَزَاءُ سَيِّئَةٍ سَيِّئَةٌ مِثْلُهَا ۖ فَمَنْ عَفَا وَأَصْلَحَ فَأَجْرُهُ عَلَى اللَّهِ ۚ إِنَّهُ لَا يُحِبُّ الظَّالِمِينَ
Esan aburu si ni aburu bi iru re. Enikeni ti o ba si samojukuro, ti o tun satunse, esan re wa lodo Allahu. Dajudaju (Allahu) ko nifee awon alabosi

Choose other languages: