Quran Apps in many lanuages:

Surah Ash-Shura Ayahs #42 Translated in Yoruba

وَالَّذِينَ اسْتَجَابُوا لِرَبِّهِمْ وَأَقَامُوا الصَّلَاةَ وَأَمْرُهُمْ شُورَىٰ بَيْنَهُمْ وَمِمَّا رَزَقْنَاهُمْ يُنْفِقُونَ
(Ohun ti o wa lodo Allahu tun wa fun) awon t’o jepe ti Oluwa won, ti won n kirun, oro ara won si je ijiroro laaarin ara won, won tun n na ninu arisiki ti A pese fun won
وَالَّذِينَ إِذَا أَصَابَهُمُ الْبَغْيُ هُمْ يَنْتَصِرُونَ
(Ohun ti o wa lodo Allahu tun wa fun) awon ti (o je pe) nigba ti won ba se abosi si won, won yoo gbesan won pada
وَجَزَاءُ سَيِّئَةٍ سَيِّئَةٌ مِثْلُهَا ۖ فَمَنْ عَفَا وَأَصْلَحَ فَأَجْرُهُ عَلَى اللَّهِ ۚ إِنَّهُ لَا يُحِبُّ الظَّالِمِينَ
Esan aburu si ni aburu bi iru re. Enikeni ti o ba si samojukuro, ti o tun satunse, esan re wa lodo Allahu. Dajudaju (Allahu) ko nifee awon alabosi
وَلَمَنِ انْتَصَرَ بَعْدَ ظُلْمِهِ فَأُولَٰئِكَ مَا عَلَيْهِمْ مِنْ سَبِيلٍ
Dajudaju eni ti o ba si gbesan leyin ti won se abosi si i, awon wonyen (ti won sabosi si), ko si ibawi kan kan fun won
إِنَّمَا السَّبِيلُ عَلَى الَّذِينَ يَظْلِمُونَ النَّاسَ وَيَبْغُونَ فِي الْأَرْضِ بِغَيْرِ الْحَقِّ ۚ أُولَٰئِكَ لَهُمْ عَذَابٌ أَلِيمٌ
Awon ti ibawi wa fun ni awon t’o n sabosi si awon eniyan, ti won tun n tayo enu-ala lori ile lai letoo. Awon wonyen ni iya eleta-elero wa fun

Choose other languages: