Quran Apps in many lanuages:

Surah As-Sajda Ayahs #26 Translated in Yoruba

وَمَنْ أَظْلَمُ مِمَّنْ ذُكِّرَ بِآيَاتِ رَبِّهِ ثُمَّ أَعْرَضَ عَنْهَا ۚ إِنَّا مِنَ الْمُجْرِمِينَ مُنْتَقِمُونَ
Ati pe ta l’o se abosi t’o tayo eni ti won fi awon ayah Wa se isiti fun, leyin naa, ti o gbunri kuro nibe? Dajudaju Awa maa gbesan lara awon elese
وَلَقَدْ آتَيْنَا مُوسَى الْكِتَابَ فَلَا تَكُنْ فِي مِرْيَةٍ مِنْ لِقَائِهِ ۖ وَجَعَلْنَاهُ هُدًى لِبَنِي إِسْرَائِيلَ
Dajudaju A fun (Anabi) Musa ni Tira. Nitori naa, ma se wa ninu iyemeji nipa bi o se pade re (iyen, ninu irin-ajo oru ati gigun sanmo). A si se Tira naa ni imona fun awon omo ’Isro’il
وَجَعَلْنَا مِنْهُمْ أَئِمَّةً يَهْدُونَ بِأَمْرِنَا لَمَّا صَبَرُوا ۖ وَكَانُوا بِآيَاتِنَا يُوقِنُونَ
Ati pe A se awon asiwaju kan ninu won ni afinimona pelu ase Wa nigba ti won se suuru. Won si n ni amodaju nipa awon ayah Wa
إِنَّ رَبَّكَ هُوَ يَفْصِلُ بَيْنَهُمْ يَوْمَ الْقِيَامَةِ فِيمَا كَانُوا فِيهِ يَخْتَلِفُونَ
Dajudaju Oluwa re, O maa se idajo laaarin won ni Ojo Ajinde nipa ohun ti won n yapa enu si
أَوَلَمْ يَهْدِ لَهُمْ كَمْ أَهْلَكْنَا مِنْ قَبْلِهِمْ مِنَ الْقُرُونِ يَمْشُونَ فِي مَسَاكِنِهِمْ ۚ إِنَّ فِي ذَٰلِكَ لَآيَاتٍ ۖ أَفَلَا يَسْمَعُونَ
Se ko foju han si won pe, meloo meloo ninu awon iran ti A ti pare siwaju won. Awon naa si n rin koja ninu awon ibugbe won! Dajudaju awon ami wa ninu iyen. Nitori naa, se won ko nii teti gboro (ododo ni)

Choose other languages: