Quran Apps in many lanuages:

Surah Ar-Rum Ayahs #8 Translated in Yoruba

فِي بِضْعِ سِنِينَ ۗ لِلَّهِ الْأَمْرُ مِنْ قَبْلُ وَمِنْ بَعْدُ ۚ وَيَوْمَئِذٍ يَفْرَحُ الْمُؤْمِنُونَ
ni odun mewaa (si igba naa). Ti Allahu ni ase ni isaaju ati ni ikeyin. Ni ojo yen, awon onigbagbo ododo maa dunnu
بِنَصْرِ اللَّهِ ۚ يَنْصُرُ مَنْ يَشَاءُ ۖ وَهُوَ الْعَزِيزُ الرَّحِيمُ
si aranse Allahu. O n saranse fun eni ti O ba fe. Oun si ni Alagbara, Asake-orun
وَعْدَ اللَّهِ ۖ لَا يُخْلِفُ اللَّهُ وَعْدَهُ وَلَٰكِنَّ أَكْثَرَ النَّاسِ لَا يَعْلَمُونَ
(Eyi je) adehun Allahu. Allahu ko si nii yapa adehun Re, sugbon opolopo awon eniyan ko mo
يَعْلَمُونَ ظَاهِرًا مِنَ الْحَيَاةِ الدُّنْيَا وَهُمْ عَنِ الْآخِرَةِ هُمْ غَافِلُونَ
Won nimo nipa gbangba ninu oro isemi aye (yii). Afonu-fora si ni won nipa Ojo Ikeyin
أَوَلَمْ يَتَفَكَّرُوا فِي أَنْفُسِهِمْ ۗ مَا خَلَقَ اللَّهُ السَّمَاوَاتِ وَالْأَرْضَ وَمَا بَيْنَهُمَا إِلَّا بِالْحَقِّ وَأَجَلٍ مُسَمًّى ۗ وَإِنَّ كَثِيرًا مِنَ النَّاسِ بِلِقَاءِ رَبِّهِمْ لَكَافِرُونَ
Se won ko ronu nipa oro ara won ni? Allahu ko seda awon sanmo, ile ati nnkan t’o wa laaarin awon mejeeji bi ko se pelu ododo ati fun gbedeke akoko kan. Dajudaju opolopo ninu awon eniyan ma ni alaigbagbo ninu ipade Oluwa won

Choose other languages: