Quran Apps in many lanuages:

Surah Ar-Rum Ayahs #10 Translated in Yoruba

وَعْدَ اللَّهِ ۖ لَا يُخْلِفُ اللَّهُ وَعْدَهُ وَلَٰكِنَّ أَكْثَرَ النَّاسِ لَا يَعْلَمُونَ
(Eyi je) adehun Allahu. Allahu ko si nii yapa adehun Re, sugbon opolopo awon eniyan ko mo
يَعْلَمُونَ ظَاهِرًا مِنَ الْحَيَاةِ الدُّنْيَا وَهُمْ عَنِ الْآخِرَةِ هُمْ غَافِلُونَ
Won nimo nipa gbangba ninu oro isemi aye (yii). Afonu-fora si ni won nipa Ojo Ikeyin
أَوَلَمْ يَتَفَكَّرُوا فِي أَنْفُسِهِمْ ۗ مَا خَلَقَ اللَّهُ السَّمَاوَاتِ وَالْأَرْضَ وَمَا بَيْنَهُمَا إِلَّا بِالْحَقِّ وَأَجَلٍ مُسَمًّى ۗ وَإِنَّ كَثِيرًا مِنَ النَّاسِ بِلِقَاءِ رَبِّهِمْ لَكَافِرُونَ
Se won ko ronu nipa oro ara won ni? Allahu ko seda awon sanmo, ile ati nnkan t’o wa laaarin awon mejeeji bi ko se pelu ododo ati fun gbedeke akoko kan. Dajudaju opolopo ninu awon eniyan ma ni alaigbagbo ninu ipade Oluwa won
أَوَلَمْ يَسِيرُوا فِي الْأَرْضِ فَيَنْظُرُوا كَيْفَ كَانَ عَاقِبَةُ الَّذِينَ مِنْ قَبْلِهِمْ ۚ كَانُوا أَشَدَّ مِنْهُمْ قُوَّةً وَأَثَارُوا الْأَرْضَ وَعَمَرُوهَا أَكْثَرَ مِمَّا عَمَرُوهَا وَجَاءَتْهُمْ رُسُلُهُمْ بِالْبَيِّنَاتِ ۖ فَمَا كَانَ اللَّهُ لِيَظْلِمَهُمْ وَلَٰكِنْ كَانُوا أَنْفُسَهُمْ يَظْلِمُونَ
Se won ko rin kiri lori ile ki won wo bi ikangun awon t’o siwaju won se ri? Won ni agbara ju won lo. Won fi ile dako. Won si lo ile fun ohun ti o po ju bi (awon ara Mokkah) se lo o. Awon Ojise won si mu awon eri t’o yanju wa ba won. Nitori naa, Allahu ko sabosi si won, sugbon emi ara won ni won n sabosi si
ثُمَّ كَانَ عَاقِبَةَ الَّذِينَ أَسَاءُوا السُّوأَىٰ أَنْ كَذَّبُوا بِآيَاتِ اللَّهِ وَكَانُوا بِهَا يَسْتَهْزِئُونَ
Leyin naa, aburu je atubotan awon t’o saburu nitori pe won pe awon ayah Allahu niro. Won si n fi se yeye

Choose other languages: