Quran Apps in many lanuages:

Surah Ar-Rum Ayahs #50 Translated in Yoruba

وَمِنْ آيَاتِهِ أَنْ يُرْسِلَ الرِّيَاحَ مُبَشِّرَاتٍ وَلِيُذِيقَكُمْ مِنْ رَحْمَتِهِ وَلِتَجْرِيَ الْفُلْكُ بِأَمْرِهِ وَلِتَبْتَغُوا مِنْ فَضْلِهِ وَلَعَلَّكُمْ تَشْكُرُونَ
Ninu awon ami Re ni pe, O n ran ategun ni iro idunnu. Ati pe nitori ki (Allahu) le fun yin to wo ninu ike Re; ati nitori ki oko oju-omi le rin loju-omi pelu ase Re; ati nitori ki e le wa ninu oore Re; ati nitori ki e le dupe
وَلَقَدْ أَرْسَلْنَا مِنْ قَبْلِكَ رُسُلًا إِلَىٰ قَوْمِهِمْ فَجَاءُوهُمْ بِالْبَيِّنَاتِ فَانْتَقَمْنَا مِنَ الَّذِينَ أَجْرَمُوا ۖ وَكَانَ حَقًّا عَلَيْنَا نَصْرُ الْمُؤْمِنِينَ
Dajudaju A ti ran awon Ojise kan nise siwaju re si awon ijo won. Won si wa ba won pelu awon eri t’o yanju. A si gbesan lara awon t’o dese. O si je eto fun wa lati se aranse fun awon onigbagbo ododo
اللَّهُ الَّذِي يُرْسِلُ الرِّيَاحَ فَتُثِيرُ سَحَابًا فَيَبْسُطُهُ فِي السَّمَاءِ كَيْفَ يَشَاءُ وَيَجْعَلُهُ كِسَفًا فَتَرَى الْوَدْقَ يَخْرُجُ مِنْ خِلَالِهِ ۖ فَإِذَا أَصَابَ بِهِ مَنْ يَشَاءُ مِنْ عِبَادِهِ إِذَا هُمْ يَسْتَبْشِرُونَ
Allahu ni Eni t’O n fi awon ategun ranse. (Ategun naa) si maa tu esujo soke. (Allahu) yo si te (esujo) sile s’oju sanmo bi O ba se fe. O si maa da a kelekele (si oju sanmo). O si maa ri ojo ti o ma maa jade laaarin re. Nigba ti O ba si ro (ojo naa) fun eni ti O ba fe ninu awon erusin Re, nigba naa won yo si maa dunnu
وَإِنْ كَانُوا مِنْ قَبْلِ أَنْ يُنَزَّلَ عَلَيْهِمْ مِنْ قَبْلِهِ لَمُبْلِسِينَ
Bi o tile je pe siwaju ki O to so o kale fun won, won ti soreti nu siwaju re
فَانْظُرْ إِلَىٰ آثَارِ رَحْمَتِ اللَّهِ كَيْفَ يُحْيِي الْأَرْضَ بَعْدَ مَوْتِهَا ۚ إِنَّ ذَٰلِكَ لَمُحْيِي الْمَوْتَىٰ ۖ وَهُوَ عَلَىٰ كُلِّ شَيْءٍ قَدِيرٌ
Nitori naa, woye si awon oripa ike Allahu, (wo) bi (Allahu) se n ta ile ji leyin ti ile ti ku. Dajudaju (Allahu) yii ni O kuku maa so awon oku di alaaye. Oun si ni Alagbara lori gbogbo nnkan

Choose other languages: