Quran Apps in many lanuages:

Surah Ar-Rum Ayahs #40 Translated in Yoruba

وَإِذَا أَذَقْنَا النَّاسَ رَحْمَةً فَرِحُوا بِهَا ۖ وَإِنْ تُصِبْهُمْ سَيِّئَةٌ بِمَا قَدَّمَتْ أَيْدِيهِمْ إِذَا هُمْ يَقْنَطُونَ
Nigba ti A ba fi ike kan to eniyan lenu wo, won yoo dunnu si i. Ti aburu kan ba si kan won nipa ohun ti owo won ti siwaju, nigba naa ni won yoo soreti nu
أَوَلَمْ يَرَوْا أَنَّ اللَّهَ يَبْسُطُ الرِّزْقَ لِمَنْ يَشَاءُ وَيَقْدِرُ ۚ إِنَّ فِي ذَٰلِكَ لَآيَاتٍ لِقَوْمٍ يُؤْمِنُونَ
Se won ko ri i pe dajudaju Allahu l’O n te oro sile fun eni ti O ba fe, (O si n) diwon re (fun eni ti O ba fe)? Dajudaju awon ami wa ninu iyen fun ijo t’o gbagbo
فَآتِ ذَا الْقُرْبَىٰ حَقَّهُ وَالْمِسْكِينَ وَابْنَ السَّبِيلِ ۚ ذَٰلِكَ خَيْرٌ لِلَّذِينَ يُرِيدُونَ وَجْهَ اللَّهِ ۖ وَأُولَٰئِكَ هُمُ الْمُفْلِحُونَ
Nitori naa, fun ebi ni eto re. (Fun) mekunnu ati onirin-ajo ti agara da (ni nnkan). Iyen loore julo fun awon t’o n fe Oju rere Allahu. Awon wonyen, awon si ni olujere
وَمَا آتَيْتُمْ مِنْ رِبًا لِيَرْبُوَ فِي أَمْوَالِ النَّاسِ فَلَا يَرْبُو عِنْدَ اللَّهِ ۖ وَمَا آتَيْتُمْ مِنْ زَكَاةٍ تُرِيدُونَ وَجْهَ اللَّهِ فَأُولَٰئِكَ هُمُ الْمُضْعِفُونَ
Ohunkohun ti e ba fun (awon eniyan) ni ebun, nitori ki o le di ele lati ara dukia awon eniyan, ko le lekun ni odo Allahu. Ohunkohun ti e ba si (fun awon eniyan) ni Zakah, ti e n fe oju rere Allahu, awon wonyen ni A maa fun ni adipele esan
اللَّهُ الَّذِي خَلَقَكُمْ ثُمَّ رَزَقَكُمْ ثُمَّ يُمِيتُكُمْ ثُمَّ يُحْيِيكُمْ ۖ هَلْ مِنْ شُرَكَائِكُمْ مَنْ يَفْعَلُ مِنْ ذَٰلِكُمْ مِنْ شَيْءٍ ۚ سُبْحَانَهُ وَتَعَالَىٰ عَمَّا يُشْرِكُونَ
Allahu, Eni ti O seda yin, leyin naa, O fun yin ni arisiki, leyin naa, O maa so yin di oku, leyin naa, O maa so yin di alaaye. Nje o wa ninu awon orisa yin eni ti o le se nnkan kan ninu iyen? Mimo ni fun Un. O ga tayo nnkan ti won n fi sebo si I

Choose other languages: