Quran Apps in many lanuages:

Surah An-Nur Ayahs #43 Translated in Yoruba

وَالَّذِينَ كَفَرُوا أَعْمَالُهُمْ كَسَرَابٍ بِقِيعَةٍ يَحْسَبُهُ الظَّمْآنُ مَاءً حَتَّىٰ إِذَا جَاءَهُ لَمْ يَجِدْهُ شَيْئًا وَوَجَدَ اللَّهَ عِنْدَهُ فَوَفَّاهُ حِسَابَهُ ۗ وَاللَّهُ سَرِيعُ الْحِسَابِ
Awon t’o sai gbagbo, awon ise won da bi ahunpeena t’o wa ni papa, ti eni ti ongbe n gbe si lero pe omi ni titi di igba ti o de sibe, ko si ba kini kan nibe. O si ba Allahu nibi (ise) re (ni orun). (Allahu) si se asepe isiro-ise re fun un. Allahu ni Oluyara nibi isiro-ise
أَوْ كَظُلُمَاتٍ فِي بَحْرٍ لُجِّيٍّ يَغْشَاهُ مَوْجٌ مِنْ فَوْقِهِ مَوْجٌ مِنْ فَوْقِهِ سَحَابٌ ۚ ظُلُمَاتٌ بَعْضُهَا فَوْقَ بَعْضٍ إِذَا أَخْرَجَ يَدَهُ لَمْ يَكَدْ يَرَاهَا ۗ وَمَنْ لَمْ يَجْعَلِ اللَّهُ لَهُ نُورًا فَمَا لَهُ مِنْ نُورٍ
Tabi (ise awon alaigbagbo) da bi awon okunkun kan ninu ibudo jijin, ti igbi omi n bo o mole, ti igbi omi miiran tun wa ni oke re, ti esujo si wa ni oke re; awon okunkun biribiri ti apa kan won wa lori apa kan (niyi). Nigba ti o ba nawo ara re jade, ko ni fee ri i. Enikeni ti Allahu ko ba fun ni imole, ko le si imole kan fun un
أَلَمْ تَرَ أَنَّ اللَّهَ يُسَبِّحُ لَهُ مَنْ فِي السَّمَاوَاتِ وَالْأَرْضِ وَالطَّيْرُ صَافَّاتٍ ۖ كُلٌّ قَدْ عَلِمَ صَلَاتَهُ وَتَسْبِيحَهُ ۗ وَاللَّهُ عَلِيمٌ بِمَا يَفْعَلُونَ
Se o o ri i pe dajudaju Allahu ni gbogbo eni t’o n be ninu awon sanmo ati lori ile n se afomo fun? Awon eye naa (n se bee) nigba ti won ba n na iye apa won? Ikookan won kuku ti mo bi o se maa kirun re ati bi o se maa se afomo re (fun Un). Allahu si ni Onimo nipa ohun ti won n se nise
وَلِلَّهِ مُلْكُ السَّمَاوَاتِ وَالْأَرْضِ ۖ وَإِلَى اللَّهِ الْمَصِيرُ
Ti Allahu ni ijoba awon sanmo ati ile. Odo Allahu si ni abo eda
أَلَمْ تَرَ أَنَّ اللَّهَ يُزْجِي سَحَابًا ثُمَّ يُؤَلِّفُ بَيْنَهُ ثُمَّ يَجْعَلُهُ رُكَامًا فَتَرَى الْوَدْقَ يَخْرُجُ مِنْ خِلَالِهِ وَيُنَزِّلُ مِنَ السَّمَاءِ مِنْ جِبَالٍ فِيهَا مِنْ بَرَدٍ فَيُصِيبُ بِهِ مَنْ يَشَاءُ وَيَصْرِفُهُ عَنْ مَنْ يَشَاءُ ۖ يَكَادُ سَنَا بَرْقِهِ يَذْهَبُ بِالْأَبْصَارِ
Se o o ri i pe dajudaju Allahu n da esujo kaakiri ni? Leyin naa O n ko o jo mora won. Leyin naa, O n gbe won gun ara won, nigba naa ni o maa ri ojo ti o maa jade lati aarin re. Lati inu sanmo, O si n so awon yiyin kan (t’o da bi) awon apata kale si ori ile aye. O n mu un kolu eni ti O ba fe. O si n seri re kuro fun eni ti O ba fe. Kiko yanranyanran monamona inu esujo si fee le fo awon oju

Choose other languages: