Quran Apps in many lanuages:

Surah An-Nisa Ayahs #65 Translated in Yoruba

وَإِذَا قِيلَ لَهُمْ تَعَالَوْا إِلَىٰ مَا أَنْزَلَ اللَّهُ وَإِلَى الرَّسُولِ رَأَيْتَ الْمُنَافِقِينَ يَصُدُّونَ عَنْكَ صُدُودًا
Nigba ti won ba so fun won pe: “E wa sibi ohun ti Allahu sokale, e wa ba Ojise.”, o maa ri awon munaafiki ti won yoo maa seri kuro lodo re taara
فَكَيْفَ إِذَا أَصَابَتْهُمْ مُصِيبَةٌ بِمَا قَدَّمَتْ أَيْدِيهِمْ ثُمَّ جَاءُوكَ يَحْلِفُونَ بِاللَّهِ إِنْ أَرَدْنَا إِلَّا إِحْسَانًا وَتَوْفِيقًا
Bawo ni o se je pe nigba ti adanwo kan ba kan won nipase ohun ti owo won ti siwaju, leyin naa won maa wa ba o, won yo si maa fi Allahu bura pe ko si ohun ti a gba lero bi ko se daadaa ati irepo
أُولَٰئِكَ الَّذِينَ يَعْلَمُ اللَّهُ مَا فِي قُلُوبِهِمْ فَأَعْرِضْ عَنْهُمْ وَعِظْهُمْ وَقُلْ لَهُمْ فِي أَنْفُسِهِمْ قَوْلًا بَلِيغًا
Awon wonyen ni awon ti Allahu mo ohun ti n be ninu okan won. Nitori naa, seri kuro lodo won. Se waasi fun won, ki o si ba won so oro t’o lagbara nipa ara won
وَمَا أَرْسَلْنَا مِنْ رَسُولٍ إِلَّا لِيُطَاعَ بِإِذْنِ اللَّهِ ۚ وَلَوْ أَنَّهُمْ إِذْ ظَلَمُوا أَنْفُسَهُمْ جَاءُوكَ فَاسْتَغْفَرُوا اللَّهَ وَاسْتَغْفَرَ لَهُمُ الرَّسُولُ لَوَجَدُوا اللَّهَ تَوَّابًا رَحِيمًا
A o ran Ojise kan nise afi nitori ki won le tele e pelu iyonda Allahu. Ti o ba je pe nigba ti won sabosi si emi ara won, won wa ba o, won si toro aforijin Allahu, ti Ojise si tun ba won toro aforijin, won iba kuku ri Allahu ni Olugba-ironupiwada, Asake-orun
فَلَا وَرَبِّكَ لَا يُؤْمِنُونَ حَتَّىٰ يُحَكِّمُوكَ فِيمَا شَجَرَ بَيْنَهُمْ ثُمَّ لَا يَجِدُوا فِي أَنْفُسِهِمْ حَرَجًا مِمَّا قَضَيْتَ وَيُسَلِّمُوا تَسْلِيمًا
Rara, Emi fi Oluwa re bura pe won ko ti i gbagbo ni ododo titi won yoo fi gba o ni oludajo lori ohun ti o ba da yanponyanrin sile laaarin won. Leyin naa, won ko nii ni ehonu kan si idajo ti o ba da. Won si maa gba patapata

Choose other languages: