Quran Apps in many lanuages:

Surah An-Nisa Ayahs #164 Translated in Yoruba

فَبِظُلْمٍ مِنَ الَّذِينَ هَادُوا حَرَّمْنَا عَلَيْهِمْ طَيِّبَاتٍ أُحِلَّتْ لَهُمْ وَبِصَدِّهِمْ عَنْ سَبِيلِ اللَّهِ كَثِيرًا
Nitori abosi lati odo awon ti won di yehudi, A se awon nnkan daadaa kan ni eewo fun won, eyi ti won se ni eto fun won (tele. A se e ni eewo fun won se) nipa bi won se n seri opolopo kuro loju ona (esin) Allahu
وَأَخْذِهِمُ الرِّبَا وَقَدْ نُهُوا عَنْهُ وَأَكْلِهِمْ أَمْوَالَ النَّاسِ بِالْبَاطِلِ ۚ وَأَعْتَدْنَا لِلْكَافِرِينَ مِنْهُمْ عَذَابًا أَلِيمًا
Ati gbigba ti won n gba owo ele, ti A si ti ko o fun won, ati jije ti won n je dukia awon eniyan lona eru. A si ti pese iya eleta-elero sile de awon alaigbagbo
لَٰكِنِ الرَّاسِخُونَ فِي الْعِلْمِ مِنْهُمْ وَالْمُؤْمِنُونَ يُؤْمِنُونَ بِمَا أُنْزِلَ إِلَيْكَ وَمَا أُنْزِلَ مِنْ قَبْلِكَ ۚ وَالْمُقِيمِينَ الصَّلَاةَ ۚ وَالْمُؤْتُونَ الزَّكَاةَ وَالْمُؤْمِنُونَ بِاللَّهِ وَالْيَوْمِ الْآخِرِ أُولَٰئِكَ سَنُؤْتِيهِمْ أَجْرًا عَظِيمًا
Sugbon awon agba ninu imo ninu won ati awon onigbagbo ododo, won gbagbo ninu ohun ti A sokale fun o ati ohun ti A sokale siwaju re, (won tun gbagbo ninu awon molaika) t’o n kirun. (Awon wonyen) ati awon t’o n yo Zakah ati awon t’o gbagbo ninu Allahu ati Ojo Ikeyin, awon wonyen ni A maa fun ni esan nla
إِنَّا أَوْحَيْنَا إِلَيْكَ كَمَا أَوْحَيْنَا إِلَىٰ نُوحٍ وَالنَّبِيِّينَ مِنْ بَعْدِهِ ۚ وَأَوْحَيْنَا إِلَىٰ إِبْرَاهِيمَ وَإِسْمَاعِيلَ وَإِسْحَاقَ وَيَعْقُوبَ وَالْأَسْبَاطِ وَعِيسَىٰ وَأَيُّوبَ وَيُونُسَ وَهَارُونَ وَسُلَيْمَانَ ۚ وَآتَيْنَا دَاوُودَ زَبُورًا
Dajudaju Awa (fi imisi) ranse si o gege bi A se fi ranse si (Anabi) Nuh ati awon Anabi (miiran) leyin re. A fi imisi ranse si (awon Anabi) ’Ibrohim, ’Ismo‘il, ’Ishaƙ, Ya‘ƙub ati awon aromodomo (re), ati (Anabi) ‘Isa, ’Ayyub, Yunus, Harun ati Sulaemon. A si fun (Anabi) Dawud ni Zabur
وَرُسُلًا قَدْ قَصَصْنَاهُمْ عَلَيْكَ مِنْ قَبْلُ وَرُسُلًا لَمْ نَقْصُصْهُمْ عَلَيْكَ ۚ وَكَلَّمَ اللَّهُ مُوسَىٰ تَكْلِيمًا
Ati awon Ojise kan ti A ti so itan won fun o siwaju pelu awon Ojise kan ti A ko so itan won fun o. Allahu si ba (Anabi) Musa soro taara

Choose other languages: