Quran Apps in many lanuages:

Surah An-Nisa Ayahs #117 Translated in Yoruba

وَلَوْلَا فَضْلُ اللَّهِ عَلَيْكَ وَرَحْمَتُهُ لَهَمَّتْ طَائِفَةٌ مِنْهُمْ أَنْ يُضِلُّوكَ وَمَا يُضِلُّونَ إِلَّا أَنْفُسَهُمْ ۖ وَمَا يَضُرُّونَكَ مِنْ شَيْءٍ ۚ وَأَنْزَلَ اللَّهُ عَلَيْكَ الْكِتَابَ وَالْحِكْمَةَ وَعَلَّمَكَ مَا لَمْ تَكُنْ تَعْلَمُ ۚ وَكَانَ فَضْلُ اللَّهِ عَلَيْكَ عَظِيمًا
Ti ki i ba se ti oore ajulo Allahu ati aanu Re ti n be lori re ni, igun kan ninu won iba ti fe si o lona. Won ko si nii si eni kan lona afi ara won. Won ko si le fi nnkan kan ko inira ba o. Allahu si so Tira ati ijinle oye (iyen, sunnah) kale fun o. O tun fi ohun ti iwo ko mo tele mo o; oore ajulo Allahu lori re je ohun t’o tobi
لَا خَيْرَ فِي كَثِيرٍ مِنْ نَجْوَاهُمْ إِلَّا مَنْ أَمَرَ بِصَدَقَةٍ أَوْ مَعْرُوفٍ أَوْ إِصْلَاحٍ بَيْنَ النَّاسِ ۚ وَمَنْ يَفْعَلْ ذَٰلِكَ ابْتِغَاءَ مَرْضَاتِ اللَّهِ فَسَوْفَ نُؤْتِيهِ أَجْرًا عَظِيمًا
Ko si oore ninu opolopo oro ikoko won afi eni ti o ba pase ore tita tabi ise rere tabi atunse laaarin awon eniyan. Enikeni ti o ba se iyen lati fi wa iyonu Allahu, laipe A maa fun un ni esan t’o tobi
وَمَنْ يُشَاقِقِ الرَّسُولَ مِنْ بَعْدِ مَا تَبَيَّنَ لَهُ الْهُدَىٰ وَيَتَّبِعْ غَيْرَ سَبِيلِ الْمُؤْمِنِينَ نُوَلِّهِ مَا تَوَلَّىٰ وَنُصْلِهِ جَهَنَّمَ ۖ وَسَاءَتْ مَصِيرًا
Enikeni ti o ba lodi si Ojise naa leyin ti imona ti foju han si i kedere, ti o tun tele ona t’o yato si ti awon onigbagbo ododo, A oo doju re ko ohun ti o doju ara re ko (ninu isina), A o si mu un wo inu ina Jahanamo. O si buru ni ikangun
إِنَّ اللَّهَ لَا يَغْفِرُ أَنْ يُشْرَكَ بِهِ وَيَغْفِرُ مَا دُونَ ذَٰلِكَ لِمَنْ يَشَاءُ ۚ وَمَنْ يُشْرِكْ بِاللَّهِ فَقَدْ ضَلَّ ضَلَالًا بَعِيدًا
Dajudaju Allahu ko nii forijin (eni ti) o ba n sebo si I. O si maa saforijin fun ese miiran yato si iyen fun eni ti O ba fe. Enikeni ti o ba n sebo si Allahu, dajudaju o ti sina ni isina t’o jinna
إِنْ يَدْعُونَ مِنْ دُونِهِ إِلَّا إِنَاثًا وَإِنْ يَدْعُونَ إِلَّا شَيْطَانًا مَرِيدًا
Won ko pe kini kan leyin Allahu bi ko se awon abo orisa. Won ko si pe kini kan bi ko se Esu oluyapa

Choose other languages: