Quran Apps in many lanuages:

Surah An-Nisa Ayahs #114 Translated in Yoruba

وَمَنْ يَعْمَلْ سُوءًا أَوْ يَظْلِمْ نَفْسَهُ ثُمَّ يَسْتَغْفِرِ اللَّهَ يَجِدِ اللَّهَ غَفُورًا رَحِيمًا
Enikeni ti o ba sise aburu kan tabi ti o sabosi si emi ara re, leyin naa ti o toro aforijin lodo Allahu, o maa ba Allahu ni Alaforijin, Alaaanu
وَمَنْ يَكْسِبْ إِثْمًا فَإِنَّمَا يَكْسِبُهُ عَلَىٰ نَفْسِهِ ۚ وَكَانَ اللَّهُ عَلِيمًا حَكِيمًا
Enikeni ti o ba da ese kan, o da a fun emi ara re. Allahu si n je Onimo, Ologbon
وَمَنْ يَكْسِبْ خَطِيئَةً أَوْ إِثْمًا ثُمَّ يَرْمِ بِهِ بَرِيئًا فَقَدِ احْتَمَلَ بُهْتَانًا وَإِثْمًا مُبِينًا
Enikeni ti o ba se asise kan tabi ese kan, leyin naa, o di i ru alaimowo-mese, o ti da oran iparomoni ati ese ponnbele
وَلَوْلَا فَضْلُ اللَّهِ عَلَيْكَ وَرَحْمَتُهُ لَهَمَّتْ طَائِفَةٌ مِنْهُمْ أَنْ يُضِلُّوكَ وَمَا يُضِلُّونَ إِلَّا أَنْفُسَهُمْ ۖ وَمَا يَضُرُّونَكَ مِنْ شَيْءٍ ۚ وَأَنْزَلَ اللَّهُ عَلَيْكَ الْكِتَابَ وَالْحِكْمَةَ وَعَلَّمَكَ مَا لَمْ تَكُنْ تَعْلَمُ ۚ وَكَانَ فَضْلُ اللَّهِ عَلَيْكَ عَظِيمًا
Ti ki i ba se ti oore ajulo Allahu ati aanu Re ti n be lori re ni, igun kan ninu won iba ti fe si o lona. Won ko si nii si eni kan lona afi ara won. Won ko si le fi nnkan kan ko inira ba o. Allahu si so Tira ati ijinle oye (iyen, sunnah) kale fun o. O tun fi ohun ti iwo ko mo tele mo o; oore ajulo Allahu lori re je ohun t’o tobi
لَا خَيْرَ فِي كَثِيرٍ مِنْ نَجْوَاهُمْ إِلَّا مَنْ أَمَرَ بِصَدَقَةٍ أَوْ مَعْرُوفٍ أَوْ إِصْلَاحٍ بَيْنَ النَّاسِ ۚ وَمَنْ يَفْعَلْ ذَٰلِكَ ابْتِغَاءَ مَرْضَاتِ اللَّهِ فَسَوْفَ نُؤْتِيهِ أَجْرًا عَظِيمًا
Ko si oore ninu opolopo oro ikoko won afi eni ti o ba pase ore tita tabi ise rere tabi atunse laaarin awon eniyan. Enikeni ti o ba se iyen lati fi wa iyonu Allahu, laipe A maa fun un ni esan t’o tobi

Choose other languages: