Quran Apps in many lanuages:

Surah An-Naml Ayahs #10 Translated in Yoruba

وَإِنَّكَ لَتُلَقَّى الْقُرْآنَ مِنْ لَدُنْ حَكِيمٍ عَلِيمٍ
Dajudaju o n gba al-Ƙur’an lati odo Ologbon, Onimo
إِذْ قَالَ مُوسَىٰ لِأَهْلِهِ إِنِّي آنَسْتُ نَارًا سَآتِيكُمْ مِنْهَا بِخَبَرٍ أَوْ آتِيكُمْ بِشِهَابٍ قَبَسٍ لَعَلَّكُمْ تَصْطَلُونَ
(Ranti) nigba ti (Anabi) Musa so fun awon eniyan re pe: “Dajudaju mo ri ina kan. Mo si maa lo mu iro kan wa fun yin lati ibe, tabi ki ng mu ogunna kan t’o n tanna wa fun yin nitori ki e le yena
فَلَمَّا جَاءَهَا نُودِيَ أَنْ بُورِكَ مَنْ فِي النَّارِ وَمَنْ حَوْلَهَا وَسُبْحَانَ اللَّهِ رَبِّ الْعَالَمِينَ
Nigba ti o de ibe, A pepe pe ki ibukun maa be fun eni ti o wa nibi ina naa ati eni ti o wa ni ayika re. Mimo si ni fun Allahu, Oluwa gbogbo eda
يَا مُوسَىٰ إِنَّهُ أَنَا اللَّهُ الْعَزِيزُ الْحَكِيمُ
Musa, dajudaju Emi ni Allahu, Alagbara, Ologbon
وَأَلْقِ عَصَاكَ ۚ فَلَمَّا رَآهَا تَهْتَزُّ كَأَنَّهَا جَانٌّ وَلَّىٰ مُدْبِرًا وَلَمْ يُعَقِّبْ ۚ يَا مُوسَىٰ لَا تَخَفْ إِنِّي لَا يَخَافُ لَدَيَّ الْمُرْسَلُونَ
Ju opa re sile. (O si se bee.) Amo nigba ti o ri i t’o n yira pada bi eni pe ejo ni, Musa peyin da, o n sa lo. Ko si pada. (Allahu so pe:) Musa, ma se paya. Dajudaju awon Ojise ki i paya lodo Mi

Choose other languages: