Quran Apps in many lanuages:

Surah An-Naml Ayahs #46 Translated in Yoruba

فَلَمَّا جَاءَتْ قِيلَ أَهَٰكَذَا عَرْشُكِ ۖ قَالَتْ كَأَنَّهُ هُوَ ۚ وَأُوتِينَا الْعِلْمَ مِنْ قَبْلِهَا وَكُنَّا مُسْلِمِينَ
Nigba ti (Bilƙis) de, won so fun un pe: “Se bi ite re se ri niyi?” O wi pe: "O da bi eni pe ohun ni." (Anabi Sulaemon si so pe): “Won ti fun wa ni imo siwaju Bilƙis. A si je musulumi.”
وَصَدَّهَا مَا كَانَتْ تَعْبُدُ مِنْ دُونِ اللَّهِ ۖ إِنَّهَا كَانَتْ مِنْ قَوْمٍ كَافِرِينَ
Ohun t’o n josin fun leyin Allahu si seri re (kuro nibi ijosin fun Allahu). Dajudaju o wa ninu ijo alaigbagbo
قِيلَ لَهَا ادْخُلِي الصَّرْحَ ۖ فَلَمَّا رَأَتْهُ حَسِبَتْهُ لُجَّةً وَكَشَفَتْ عَنْ سَاقَيْهَا ۚ قَالَ إِنَّهُ صَرْحٌ مُمَرَّدٌ مِنْ قَوَارِيرَ ۗ قَالَتْ رَبِّ إِنِّي ظَلَمْتُ نَفْسِي وَأَسْلَمْتُ مَعَ سُلَيْمَانَ لِلَّهِ رَبِّ الْعَالَمِينَ
Won so fun un pe: “Wo inu aafin.” Nigba ti o ri i, o se bi ibudo ni. O si ka aso kuro ni ojugun re mejeeji. (Anabi Sulaemon) so pe: “Dajudaju aafin ti a se rigidin pelu dingi ni.” (Bilƙis) so pe: "Oluwa mi, dajudaju mo sabosi si emi ara mi. Mo si di musulumi pelu (Anabi) Sulaemon, fun Allahu, Oluwa gbogbo eda
وَلَقَدْ أَرْسَلْنَا إِلَىٰ ثَمُودَ أَخَاهُمْ صَالِحًا أَنِ اعْبُدُوا اللَّهَ فَإِذَا هُمْ فَرِيقَانِ يَخْتَصِمُونَ
Dajudaju A ti ranse si ijo Thamud. (A ran) arakunrin won, Solih (nise si won), pe: "E josin fun Allahu." Nigba naa ni won pin si ijo meji, t’o n bara won jiyan
قَالَ يَا قَوْمِ لِمَ تَسْتَعْجِلُونَ بِالسَّيِّئَةِ قَبْلَ الْحَسَنَةِ ۖ لَوْلَا تَسْتَغْفِرُونَ اللَّهَ لَعَلَّكُمْ تُرْحَمُونَ
O so pe: “Eyin ijo mi, nitori ki ni e se n wa (iya) aburu pelu ikanju siwaju (ohun) rere (t’o ye ki e mu se nise)? E o se toro aforijin lodo Allahu nitori ki Won le saanu yin?”

Choose other languages: