Quran Apps in many lanuages:

Surah Al-Qasas Ayahs #45 Translated in Yoruba

وَجَعَلْنَاهُمْ أَئِمَّةً يَدْعُونَ إِلَى النَّارِ ۖ وَيَوْمَ الْقِيَامَةِ لَا يُنْصَرُونَ
A se won ni asiwaju t’o n pepe sinu Ina. Ti o ba si di Ojo Ajinde, A o nii ran won lowo
وَأَتْبَعْنَاهُمْ فِي هَٰذِهِ الدُّنْيَا لَعْنَةً ۖ وَيَوْمَ الْقِيَامَةِ هُمْ مِنَ الْمَقْبُوحِينَ
Ati pe A fi egun topa won ni ile aye yii. Ni Ojo Ajinde, won yo si wa ninu awon eni iparun
وَلَقَدْ آتَيْنَا مُوسَى الْكِتَابَ مِنْ بَعْدِ مَا أَهْلَكْنَا الْقُرُونَ الْأُولَىٰ بَصَائِرَ لِلنَّاسِ وَهُدًى وَرَحْمَةً لَعَلَّهُمْ يَتَذَكَّرُونَ
Dajudaju A ti fun (Anabi) Musa ni Tira leyin igba ti A ti pa awon ijo akoko re. (Tira naa je) ariwoye fun awon eniyan, imona ati ike nitori ki won le lo iranti
وَمَا كُنْتَ بِجَانِبِ الْغَرْبِيِّ إِذْ قَضَيْنَا إِلَىٰ مُوسَى الْأَمْرَ وَمَا كُنْتَ مِنَ الشَّاهِدِينَ
Iwo ko si ni eba iwo-oorun nigba ti A fi oro naa ranse si (Anabi) Musa. Ati pe iwo ko si ninu awon t’o wa nibe
وَلَٰكِنَّا أَنْشَأْنَا قُرُونًا فَتَطَاوَلَ عَلَيْهِمُ الْعُمُرُ ۚ وَمَا كُنْتَ ثَاوِيًا فِي أَهْلِ مَدْيَنَ تَتْلُو عَلَيْهِمْ آيَاتِنَا وَلَٰكِنَّا كُنَّا مُرْسِلِينَ
Sugbon A seda awon iran kan ti emi won gun. O o kuku gbe laaarin ara ilu Modyan, ti o n ke awon ayah Wa fun won, sugbon Awa l’a n ran awon Ojise nise

Choose other languages: