Quran Apps in many lanuages:

Surah Al-Qasas Ayahs #15 Translated in Yoruba

وَقَالَتْ لِأُخْتِهِ قُصِّيهِ ۖ فَبَصُرَتْ بِهِ عَنْ جُنُبٍ وَهُمْ لَا يَشْعُرُونَ
O si so fun arabinrin re pe: “Topa re lo.” O si n wo o lati ibi t’o jinna. Won ko si fura (si i)
وَحَرَّمْنَا عَلَيْهِ الْمَرَاضِعَ مِنْ قَبْلُ فَقَالَتْ هَلْ أَدُلُّكُمْ عَلَىٰ أَهْلِ بَيْتٍ يَكْفُلُونَهُ لَكُمْ وَهُمْ لَهُ نَاصِحُونَ
A ko si je ki o mu oyan (miiran) siwaju (tiya re.) Arabinrin re si wi pe: “Se ki ng fi ara ile kan han yin, ti o maa gba a to fun yin? Won yo si je olutoju re.”
فَرَدَدْنَاهُ إِلَىٰ أُمِّهِ كَيْ تَقَرَّ عَيْنُهَا وَلَا تَحْزَنَ وَلِتَعْلَمَ أَنَّ وَعْدَ اللَّهِ حَقٌّ وَلَٰكِنَّ أَكْثَرَهُمْ لَا يَعْلَمُونَ
A si da a pada si odo iya re nitori ki oju re le tutu (fun idunnu) ati nitori ki o ma baa banuje. Ati pe nitori ki o le mo pe dajudaju adehun Allahu, ododo ni, sugbon opolopo won ni ko mo
وَلَمَّا بَلَغَ أَشُدَّهُ وَاسْتَوَىٰ آتَيْنَاهُ حُكْمًا وَعِلْمًا ۚ وَكَذَٰلِكَ نَجْزِي الْمُحْسِنِينَ
Nigba t’o dagba, t’o di gende, A fun un ni ogbon ati imo. Bayen ni A se n san awon oluse-rere ni esan
وَدَخَلَ الْمَدِينَةَ عَلَىٰ حِينِ غَفْلَةٍ مِنْ أَهْلِهَا فَوَجَدَ فِيهَا رَجُلَيْنِ يَقْتَتِلَانِ هَٰذَا مِنْ شِيعَتِهِ وَهَٰذَا مِنْ عَدُوِّهِ ۖ فَاسْتَغَاثَهُ الَّذِي مِنْ شِيعَتِهِ عَلَى الَّذِي مِنْ عَدُوِّهِ فَوَكَزَهُ مُوسَىٰ فَقَضَىٰ عَلَيْهِ ۖ قَالَ هَٰذَا مِنْ عَمَلِ الشَّيْطَانِ ۖ إِنَّهُ عَدُوٌّ مُضِلٌّ مُبِينٌ
O wo inu ilu nigba ti awon ara ilu ti gbagbe (nipa oro re). O ri awon okunrin meji kan ti won n ja. Eyi wa lati inu iran re. Eyi si wa lati (inu iran) ota re. Eyi ti o wa lati inu iran re wa iranlowo re lori eyi ti o wa lati (inu iran) ota re. Musa kan an ni ese. O si pa a. O so pe: “Eyi wa ninu ise Esu. Dajudaju (esu) ni ota asini-lona ponnbele.”

Choose other languages: