Quran Apps in many lanuages:

Surah Al-Maeda Ayahs #47 Translated in Yoruba

وَكَيْفَ يُحَكِّمُونَكَ وَعِنْدَهُمُ التَّوْرَاةُ فِيهَا حُكْمُ اللَّهِ ثُمَّ يَتَوَلَّوْنَ مِنْ بَعْدِ ذَٰلِكَ ۚ وَمَا أُولَٰئِكَ بِالْمُؤْمِنِينَ
Bawo ni won a se fi o se adajo, nigba ti o je pe Taorah wa lodo won. Idajo Allahu si wa ninu re. Leyin naa, won n peyin da leyin iyen. Awon wonyen ki i si se onigbagbo ododo
إِنَّا أَنْزَلْنَا التَّوْرَاةَ فِيهَا هُدًى وَنُورٌ ۚ يَحْكُمُ بِهَا النَّبِيُّونَ الَّذِينَ أَسْلَمُوا لِلَّذِينَ هَادُوا وَالرَّبَّانِيُّونَ وَالْأَحْبَارُ بِمَا اسْتُحْفِظُوا مِنْ كِتَابِ اللَّهِ وَكَانُوا عَلَيْهِ شُهَدَاءَ ۚ فَلَا تَخْشَوُا النَّاسَ وَاخْشَوْنِ وَلَا تَشْتَرُوا بِآيَاتِي ثَمَنًا قَلِيلًا ۚ وَمَنْ لَمْ يَحْكُمْ بِمَا أَنْزَلَ اللَّهُ فَأُولَٰئِكَ هُمُ الْكَافِرُونَ
Dajudaju Awa so Taorah kale. Imona ati imole n be ninu re. Awon Anabi ti won je musulumi n fi se idajo fun awon t’o di yehudi. Bee naa ni awon alufaa ati awon amofin (n fi se idajo) nitori ohun ti A ni ki won so ninu tira Allahu. Won si je elerii lori re. Nitori naa, ma se paya eniyan. E paya Mi. E ma se ta awon ayah Mi ni owo kekere. Enikeni ti ko ba sedajo pelu ohun ti Allahu sokale, awon wonyen ni alaigbagbo
وَكَتَبْنَا عَلَيْهِمْ فِيهَا أَنَّ النَّفْسَ بِالنَّفْسِ وَالْعَيْنَ بِالْعَيْنِ وَالْأَنْفَ بِالْأَنْفِ وَالْأُذُنَ بِالْأُذُنِ وَالسِّنَّ بِالسِّنِّ وَالْجُرُوحَ قِصَاصٌ ۚ فَمَنْ تَصَدَّقَ بِهِ فَهُوَ كَفَّارَةٌ لَهُ ۚ وَمَنْ لَمْ يَحْكُمْ بِمَا أَنْزَلَ اللَّهُ فَأُولَٰئِكَ هُمُ الظَّالِمُونَ
A si se e ni ofin sinu re pe dajudaju emi fun emi, oju fun oju, imu fun imu, eti fun eti ati eyin fun eyin. Ofin esan gbigba si wa fun oju-ogbe. Enikeni ti o ba si yonda igbesan, o si maa je ipesere fun un. Enikeni ti ko ba sedajo pelu ohun ti Allahu sokale, awon wonyen ni alabosi
وَقَفَّيْنَا عَلَىٰ آثَارِهِمْ بِعِيسَى ابْنِ مَرْيَمَ مُصَدِّقًا لِمَا بَيْنَ يَدَيْهِ مِنَ التَّوْرَاةِ ۖ وَآتَيْنَاهُ الْإِنْجِيلَ فِيهِ هُدًى وَنُورٌ وَمُصَدِّقًا لِمَا بَيْنَ يَدَيْهِ مِنَ التَّوْرَاةِ وَهُدًى وَمَوْعِظَةً لِلْمُتَّقِينَ
A fi ‘Isa omo Moryam tele oripa won (iyen, awon Anabi ti won je musulumi); ti o n fi ohun t’o je ododo rinle nipa eyi t’o siwaju re ninu Taorah. A si fun un ni ’Injil. Imona ati imole wa ninu re, ti o n fi ohun t’o je ododo rinle nipa eyi t’o siwaju re ninu Taorah. (O je) imona ati waasi fun awon oluberu (Allahu ni asiko tire)
وَلْيَحْكُمْ أَهْلُ الْإِنْجِيلِ بِمَا أَنْزَلَ اللَّهُ فِيهِ ۚ وَمَنْ لَمْ يَحْكُمْ بِمَا أَنْزَلَ اللَّهُ فَأُولَٰئِكَ هُمُ الْفَاسِقُونَ
Ki awon ti A fun ni ’Injil sedajo pelu ohun ti Allahu sokale ninu re. Enikeni ti ko ba sedajo pelu ohun ti Allahu sokale, awon wonyen ni obileje

Choose other languages: