Quran Apps in many lanuages:

Surah Al-Maeda Ayahs #5 Translated in Yoruba

5:1
يَا أَيُّهَا الَّذِينَ آمَنُوا أَوْفُوا بِالْعُقُودِ ۚ أُحِلَّتْ لَكُمْ بَهِيمَةُ الْأَنْعَامِ إِلَّا مَا يُتْلَىٰ عَلَيْكُمْ غَيْرَ مُحِلِّي الصَّيْدِ وَأَنْتُمْ حُرُمٌ ۗ إِنَّ اللَّهَ يَحْكُمُ مَا يُرِيدُ
Eyin ti e gbagbo ni ododo, e mu awon adehun se. Won se awon eran-osin ni eto fun yin afi eyi ti won ba n ka fun yin (ni eewo), lai nii so idode eranko di eto nigba ti e ba wa ninu aso hurumi. Dajudaju Allahu n se idajo ohun ti O ba fe
5:2
يَا أَيُّهَا الَّذِينَ آمَنُوا لَا تُحِلُّوا شَعَائِرَ اللَّهِ وَلَا الشَّهْرَ الْحَرَامَ وَلَا الْهَدْيَ وَلَا الْقَلَائِدَ وَلَا آمِّينَ الْبَيْتَ الْحَرَامَ يَبْتَغُونَ فَضْلًا مِنْ رَبِّهِمْ وَرِضْوَانًا ۚ وَإِذَا حَلَلْتُمْ فَاصْطَادُوا ۚ وَلَا يَجْرِمَنَّكُمْ شَنَآنُ قَوْمٍ أَنْ صَدُّوكُمْ عَنِ الْمَسْجِدِ الْحَرَامِ أَنْ تَعْتَدُوا ۘ وَتَعَاوَنُوا عَلَى الْبِرِّ وَالتَّقْوَىٰ ۖ وَلَا تَعَاوَنُوا عَلَى الْإِثْمِ وَالْعُدْوَانِ ۚ وَاتَّقُوا اللَّهَ ۖ إِنَّ اللَّهَ شَدِيدُ الْعِقَابِ
Eyin ti e gbagbo ni ododo, e ma se ru ofin awon nnkan arisami ti Allahu gbe kale fun esin Re. E ma se so osu owo di eto (fun ogun esin), E ma se idiwo fun awon eran ore (ti won ko sami si lorun) ati (awon eran ore) ti won sami si lorun. E ma se idiwo fun awon t’o n gbero lati lo si Ile Haram, ti won n wa oore ajulo ati iyonu lati odo Oluwa won. Ti e ba si ti tura sile ninu aso hurumi, nigba naa e (le) dode (eranko). E ma se je ki ikorira awon eniyan kan ti yin lati tayo enu-ala nitori pe won se yin lori kuro ni Mosalasi Haram. E ran ara yin lowo lori ise rere ati iberu Allahu. E ma se ran ara yin lowo lori (iwa) ese ati itayo enu-ala. E beru Allahu. Dajudaju Allahu le (nibi) iya
5:3
حُرِّمَتْ عَلَيْكُمُ الْمَيْتَةُ وَالدَّمُ وَلَحْمُ الْخِنْزِيرِ وَمَا أُهِلَّ لِغَيْرِ اللَّهِ بِهِ وَالْمُنْخَنِقَةُ وَالْمَوْقُوذَةُ وَالْمُتَرَدِّيَةُ وَالنَّطِيحَةُ وَمَا أَكَلَ السَّبُعُ إِلَّا مَا ذَكَّيْتُمْ وَمَا ذُبِحَ عَلَى النُّصُبِ وَأَنْ تَسْتَقْسِمُوا بِالْأَزْلَامِ ۚ ذَٰلِكُمْ فِسْقٌ ۗ الْيَوْمَ يَئِسَ الَّذِينَ كَفَرُوا مِنْ دِينِكُمْ فَلَا تَخْشَوْهُمْ وَاخْشَوْنِ ۚ الْيَوْمَ أَكْمَلْتُ لَكُمْ دِينَكُمْ وَأَتْمَمْتُ عَلَيْكُمْ نِعْمَتِي وَرَضِيتُ لَكُمُ الْإِسْلَامَ دِينًا ۚ فَمَنِ اضْطُرَّ فِي مَخْمَصَةٍ غَيْرَ مُتَجَانِفٍ لِإِثْمٍ ۙ فَإِنَّ اللَّهَ غَفُورٌ رَحِيمٌ
A se e ni eewo fun yin eran okunbete, ati eje, ati eran elede, ati eyi ti won pa pelu oruko ti ki i se Allahu, ati eran ti won fun lorun pa, ati eran ti won lu pa, ati eran ti o re lule ku, ati eran ti won kan pa ati eyi ti eranko abijawara je ku afi eyi ti e ba ri du (siwaju ki o to ku) ati eyi ti won pa sidii orisa. Eewo si ni fun yin lati yese wo. Iwonyi ni ibaje. Lonii ni awon t’o sai gbagbo soreti nu nipa esin yin. Nitori naa, e ma se paya won. E paya Mi. Mo pari esin yin fun yin lonii. Mo si se asepe idera Mi fun yin. Mo si yonu si ’Islam ni esin fun yin. Nitori naa, enikeni ti won ba ko sinu inira ebi (lati je eran eewo), yato si olufinnufindo-dese, dajudaju Allahu ni Alaforijin, Asake-orun
5:4
يَسْأَلُونَكَ مَاذَا أُحِلَّ لَهُمْ ۖ قُلْ أُحِلَّ لَكُمُ الطَّيِّبَاتُ ۙ وَمَا عَلَّمْتُمْ مِنَ الْجَوَارِحِ مُكَلِّبِينَ تُعَلِّمُونَهُنَّ مِمَّا عَلَّمَكُمُ اللَّهُ ۖ فَكُلُوا مِمَّا أَمْسَكْنَ عَلَيْكُمْ وَاذْكُرُوا اسْمَ اللَّهِ عَلَيْهِ ۖ وَاتَّقُوا اللَّهَ ۚ إِنَّ اللَّهَ سَرِيعُ الْحِسَابِ
Won n bi o leere pe: "Ki ni Won se ni eto fun won?" So pe: “Won se awon nnkan daadaa ni eto fun yin ati (eran ti e pa nipase) eyi ti e ko ni eko (idode) ninu awon eranko ati eye ti n dode. E ko awon aja lekoo idode, ki e ko won ninu ohun ti Allahu fi mo yin. Nitori naa, e je ninu ohun ti won ba pa fun yin, ki e si se bismillah si i . E beru Allahu. Dajudaju Allahu ni Oluyara nibi isiro-ise
5:5
الْيَوْمَ أُحِلَّ لَكُمُ الطَّيِّبَاتُ ۖ وَطَعَامُ الَّذِينَ أُوتُوا الْكِتَابَ حِلٌّ لَكُمْ وَطَعَامُكُمْ حِلٌّ لَهُمْ ۖ وَالْمُحْصَنَاتُ مِنَ الْمُؤْمِنَاتِ وَالْمُحْصَنَاتُ مِنَ الَّذِينَ أُوتُوا الْكِتَابَ مِنْ قَبْلِكُمْ إِذَا آتَيْتُمُوهُنَّ أُجُورَهُنَّ مُحْصِنِينَ غَيْرَ مُسَافِحِينَ وَلَا مُتَّخِذِي أَخْدَانٍ ۗ وَمَنْ يَكْفُرْ بِالْإِيمَانِ فَقَدْ حَبِطَ عَمَلُهُ وَهُوَ فِي الْآخِرَةِ مِنَ الْخَاسِرِينَ
Won se awon nnkan daadaa ni eto fun yin lonii. Ati ounje awon ti A fun ni tira, eto ni fun yin.1 Ounje tiyin naa, eto ni fun won. (Eto ni fun yin lati fe) awon olominira ninu awon onigbagbo ododo lobinrin ati awon olominira lobinrin ninu awon ti A fun ni tira siwaju yin, nigba ti e ba ti fun won ni sodaaki won; e fe won ni fife (bi ’Islam se ni ki e fe iyawo), lai nii ba won se sina (siwaju yigi) lai si nii yan won lale.2 Enikeni ti o ba lodi si igbagbo ododo, ise re ti baje. Ni Ojo Ikeyin, o si maa wa ninu awon eni ofo. orisa ibere ati idawole kan ti awon oyinbo aborisa n pe ni Janus ni won fi gbe osu ati odun January kale. Awon kristieni si tewo gba a lowo won. Musulumi yo si maa je musulumi lori gbigba oro Allahu gbo ni ododo. Ti iru musulumi yii ba tun wa ba awon kristieni da si odun January lai si siju wo awon ewu nla ti ko se e janiyan t’o tun ro mo igbeyawo. Dandan si ni fun wa lati lo ayah papo mora won ni ona ti ko fi nii ja si pe musulumi tele itumo oju-oro nikan ni iyapa si itumo oju oro miiran. Ni akoko na ninu surah al-Baƙorah

Choose other languages: