Quran Apps in many lanuages:

Surah Al-Maeda Ayahs #119 Translated in Yoruba

قَالَ اللَّهُ إِنِّي مُنَزِّلُهَا عَلَيْكُمْ ۖ فَمَنْ يَكْفُرْ بَعْدُ مِنْكُمْ فَإِنِّي أُعَذِّبُهُ عَذَابًا لَا أُعَذِّبُهُ أَحَدًا مِنَ الْعَالَمِينَ
Allahu so pe: “Dajudaju Emi yoo so o kale fun yin. Sugbon enikeni ti o ba sai gbagbo leyin naa ninu yin, dajudaju Mo maa je e niya kan ti Mi o fi je eni kan ri ninu gbogbo eda.”
وَإِذْ قَالَ اللَّهُ يَا عِيسَى ابْنَ مَرْيَمَ أَأَنْتَ قُلْتَ لِلنَّاسِ اتَّخِذُونِي وَأُمِّيَ إِلَٰهَيْنِ مِنْ دُونِ اللَّهِ ۖ قَالَ سُبْحَانَكَ مَا يَكُونُ لِي أَنْ أَقُولَ مَا لَيْسَ لِي بِحَقٍّ ۚ إِنْ كُنْتُ قُلْتُهُ فَقَدْ عَلِمْتَهُ ۚ تَعْلَمُ مَا فِي نَفْسِي وَلَا أَعْلَمُ مَا فِي نَفْسِكَ ۚ إِنَّكَ أَنْتَ عَلَّامُ الْغُيُوبِ
(Ranti) nigba ti Allahu so pe: “‘Isa omo Moryam, se iwo l’o so fun awon eniyan pe: "E mu emi ati iya mi ni olohun meji ti e oo maa josin fun leyin Allahu?" O so pe: "Mimo ni fun O, ko to fun mi lati so ohun ti emi ko letoo (si lati so). Ti mo ba so bee, O kuku ti mo. O mo ohun ti n be ninu emi mi. Ng o si mo ohun ti n be ninu emi Re. Dajudaju Iwo ni Onimo nipa awon ikoko
مَا قُلْتُ لَهُمْ إِلَّا مَا أَمَرْتَنِي بِهِ أَنِ اعْبُدُوا اللَّهَ رَبِّي وَرَبَّكُمْ ۚ وَكُنْتُ عَلَيْهِمْ شَهِيدًا مَا دُمْتُ فِيهِمْ ۖ فَلَمَّا تَوَفَّيْتَنِي كُنْتَ أَنْتَ الرَّقِيبَ عَلَيْهِمْ ۚ وَأَنْتَ عَلَىٰ كُلِّ شَيْءٍ شَهِيدٌ
Emi ko so ohun kan fun won bi ko se ohun ti O pa mi lase re pe: "E josin fun Allahu, Oluwa mi ati Oluwa yin." Mo si je elerii lori won niwon igba ti mo n be laaarin won. Sugbon nigba ti O gba mi kuro lowo won, Iwo ni Oluso lori won. Iwo si ni Arinu-rode gbogbo nnkan
إِنْ تُعَذِّبْهُمْ فَإِنَّهُمْ عِبَادُكَ ۖ وَإِنْ تَغْفِرْ لَهُمْ فَإِنَّكَ أَنْتَ الْعَزِيزُ الْحَكِيمُ
Ti O ba je won niya, dajudaju eru Re ni won. Ti O ba si fori jin won, dajudaju Iwo, Iwo ni Alagbara, Ologbon
قَالَ اللَّهُ هَٰذَا يَوْمُ يَنْفَعُ الصَّادِقِينَ صِدْقُهُمْ ۚ لَهُمْ جَنَّاتٌ تَجْرِي مِنْ تَحْتِهَا الْأَنْهَارُ خَالِدِينَ فِيهَا أَبَدًا ۚ رَضِيَ اللَّهُ عَنْهُمْ وَرَضُوا عَنْهُ ۚ ذَٰلِكَ الْفَوْزُ الْعَظِيمُ
Allahu so pe: “Eyi ni ojo ti ododo awon olododo yoo se won ni anfaani. Awon Ogba Idera kan ti awon odo n san ni isale re n be fun won. Olusegbere ni won ninu re titi laelae. Allahu yonu si won. Won si yonu si (ohun ti Allahu fun won). Iyen ni erenje nla

Choose other languages: