Quran Apps in many lanuages:

Surah Al-Kahf Ayahs #82 Translated in Yoruba

قَالَ هَٰذَا فِرَاقُ بَيْنِي وَبَيْنِكَ ۚ سَأُنَبِّئُكَ بِتَأْوِيلِ مَا لَمْ تَسْتَطِعْ عَلَيْهِ صَبْرًا
(Kidr) so pe: “Eyi ni opinya laaarin emi ati iwo. Mo si maa fun o ni itumo ohun ti o o le se suuru lori re.”
أَمَّا السَّفِينَةُ فَكَانَتْ لِمَسَاكِينَ يَعْمَلُونَ فِي الْبَحْرِ فَأَرَدْتُ أَنْ أَعِيبَهَا وَكَانَ وَرَاءَهُمْ مَلِكٌ يَأْخُذُ كُلَّ سَفِينَةٍ غَصْبًا
Ni ti oko oju-omi, o je ti awon mekunnu ti won n sise lori omi. Mo si fe lati fi alebu kan an (nitori pe) oba kan wa niwaju won t’o n gba gbogbo oko oju-omi pelu ipa
وَأَمَّا الْغُلَامُ فَكَانَ أَبَوَاهُ مُؤْمِنَيْنِ فَخَشِينَا أَنْ يُرْهِقَهُمَا طُغْيَانًا وَكُفْرًا
Ni ti omodekunrin naa, awon obi re mejeeji je onigbagbo ododo. A si n beru pe ki o maa ko itayo enu-ala ati aigbagbo ba awon mejeeji
فَأَرَدْنَا أَنْ يُبْدِلَهُمَا رَبُّهُمَا خَيْرًا مِنْهُ زَكَاةً وَأَقْرَبَ رُحْمًا
Nitori naa, A fe ki Oluwa awon mejeeji paaro re fun won pelu (eyi) t’o loore ju u lo ni ti mimo (ninu ese) ati (eyi) t’o sunmo ju u lo ni ti ike
وَأَمَّا الْجِدَارُ فَكَانَ لِغُلَامَيْنِ يَتِيمَيْنِ فِي الْمَدِينَةِ وَكَانَ تَحْتَهُ كَنْزٌ لَهُمَا وَكَانَ أَبُوهُمَا صَالِحًا فَأَرَادَ رَبُّكَ أَنْ يَبْلُغَا أَشُدَّهُمَا وَيَسْتَخْرِجَا كَنْزَهُمَا رَحْمَةً مِنْ رَبِّكَ ۚ وَمَا فَعَلْتُهُ عَنْ أَمْرِي ۚ ذَٰلِكَ تَأْوِيلُ مَا لَمْ تَسْطِعْ عَلَيْهِ صَبْرًا
Nipa ti ogiri, o je ti awon omodekunrin, omo orukan meji kan ninu ilu naa. Apoti-oro kan si n be fun awon mejeeji labe ogiri naa. Baba awon mejeeji si je eni rere. Nitori naa, Oluwa re fe ki awon mejeeji dagba (ba dukia naa), ki won si hu dukia won jade (ki o le je) ike kan lati odo Oluwa re. Mi o da a se lati odo ara mi; (Allahu l’O pa mi lase re). Iyen ni itumo ohun ti o o le se suuru fun

Choose other languages: