Quran Apps in many lanuages:

Surah Al-Kahf Ayahs #74 Translated in Yoruba

قَالَ فَإِنِ اتَّبَعْتَنِي فَلَا تَسْأَلْنِي عَنْ شَيْءٍ حَتَّىٰ أُحْدِثَ لَكَ مِنْهُ ذِكْرًا
(Kidr) so pe: “Ti o ba tele mi, ma se bi mi ni ibeere nipa nnkan kan titi mo fi maa koko mu iranti wa fun o nipa re.”
فَانْطَلَقَا حَتَّىٰ إِذَا رَكِبَا فِي السَّفِينَةِ خَرَقَهَا ۖ قَالَ أَخَرَقْتَهَا لِتُغْرِقَ أَهْلَهَا لَقَدْ جِئْتَ شَيْئًا إِمْرًا
Nitori naa, awon mejeeji lo titi di igba ti won fi wo inu oko oju-omi. (Kidr) si da oko naa lu. (Anabi Musa) so pe: “O se da a lu, (se) ki awon ero re le te ri ni? Dajudaju o ti se nnkan aburu kan!”
قَالَ أَلَمْ أَقُلْ إِنَّكَ لَنْ تَسْتَطِيعَ مَعِيَ صَبْرًا
(Kidr) so pe: “Nje mi o so fun o pe dajudaju o o nii le se suuru pelu mi.”
قَالَ لَا تُؤَاخِذْنِي بِمَا نَسِيتُ وَلَا تُرْهِقْنِي مِنْ أَمْرِي عُسْرًا
(Anabi Musa) so pe: “Ma se ba mi wi nipa ohun ti mo gbagbe. Ma si se ko inira ba mi ninu oro (irin-ajo) mi (pelu re).”
فَانْطَلَقَا حَتَّىٰ إِذَا لَقِيَا غُلَامًا فَقَتَلَهُ قَالَ أَقَتَلْتَ نَفْسًا زَكِيَّةً بِغَيْرِ نَفْسٍ لَقَدْ جِئْتَ شَيْئًا نُكْرًا
Leyin naa, awon mejeeji lo titi di igba ti won fi pade omodekunrin kan. (Kidr) si pa a. (Anabi Musa) so pe: “O se pa emi (eniyan) mimo, lai gba emi? Dajudaju o ti se nnkan t’o buru o.”

Choose other languages: