Quran Apps in many lanuages:

Surah Al-Kahf Ayahs #77 Translated in Yoruba

قَالَ لَا تُؤَاخِذْنِي بِمَا نَسِيتُ وَلَا تُرْهِقْنِي مِنْ أَمْرِي عُسْرًا
(Anabi Musa) so pe: “Ma se ba mi wi nipa ohun ti mo gbagbe. Ma si se ko inira ba mi ninu oro (irin-ajo) mi (pelu re).”
فَانْطَلَقَا حَتَّىٰ إِذَا لَقِيَا غُلَامًا فَقَتَلَهُ قَالَ أَقَتَلْتَ نَفْسًا زَكِيَّةً بِغَيْرِ نَفْسٍ لَقَدْ جِئْتَ شَيْئًا نُكْرًا
Leyin naa, awon mejeeji lo titi di igba ti won fi pade omodekunrin kan. (Kidr) si pa a. (Anabi Musa) so pe: “O se pa emi (eniyan) mimo, lai gba emi? Dajudaju o ti se nnkan t’o buru o.”
قَالَ أَلَمْ أَقُلْ لَكَ إِنَّكَ لَنْ تَسْتَطِيعَ مَعِيَ صَبْرًا
(Kidr) so pe: “Nje mi o so fun o pe dajudaju o o nii le se suuru pelu mi.”
قَالَ إِنْ سَأَلْتُكَ عَنْ شَيْءٍ بَعْدَهَا فَلَا تُصَاحِبْنِي ۖ قَدْ بَلَغْتَ مِنْ لَدُنِّي عُذْرًا
(Anabi Musa) so pe: “Ti mo ba tun bi o nipa kini kan leyin re, ma se ba mi rin mo. Dajudaju o ti mu awawi de opin lodo mi.”
فَانْطَلَقَا حَتَّىٰ إِذَا أَتَيَا أَهْلَ قَرْيَةٍ اسْتَطْعَمَا أَهْلَهَا فَأَبَوْا أَنْ يُضَيِّفُوهُمَا فَوَجَدَا فِيهَا جِدَارًا يُرِيدُ أَنْ يَنْقَضَّ فَأَقَامَهُ ۖ قَالَ لَوْ شِئْتَ لَاتَّخَذْتَ عَلَيْهِ أَجْرًا
Leyin naa, awon mejeeji lo titi di igba ti won de odo awon ara ilu kan. Won toro ounje lodo awon ara ilu naa. Won si ko lati se won ni alejo. Awon mejeeji si ba ogiri kan nibe ti o fe wo. (Kidr) si gbe e dide. (Anabi Musa) so pe: “Ti o ba je pe o ba fe, o o ba si gba owo-oya lori re.”

Choose other languages: