Quran Apps in many lanuages:

Surah Al-Kahf Ayahs #58 Translated in Yoruba

وَلَقَدْ صَرَّفْنَا فِي هَٰذَا الْقُرْآنِ لِلنَّاسِ مِنْ كُلِّ مَثَلٍ ۚ وَكَانَ الْإِنْسَانُ أَكْثَرَ شَيْءٍ جَدَلًا
Dajudaju A ti se alaye oniran-anran sinu al-Ƙur’an fun awon eniyan pelu gbogbo akawe. Eniyan si je alatako pupo ju ohunkohun lo
وَمَا مَنَعَ النَّاسَ أَنْ يُؤْمِنُوا إِذْ جَاءَهُمُ الْهُدَىٰ وَيَسْتَغْفِرُوا رَبَّهُمْ إِلَّا أَنْ تَأْتِيَهُمْ سُنَّةُ الْأَوَّلِينَ أَوْ يَأْتِيَهُمُ الْعَذَابُ قُبُلًا
Ko si ohun t’o di awon eniyan lowo lati gbagbo nigba ti imona de ba won, (ko si si ohun t’o di won lowo lati) toro aforijin Oluwa won, bi ko se pe (won fe) ki ise (Allahu nipa iparun) awon eni akoko de ba awon naa tabi ki iya de ba won ni ojukoju
وَمَا نُرْسِلُ الْمُرْسَلِينَ إِلَّا مُبَشِّرِينَ وَمُنْذِرِينَ ۚ وَيُجَادِلُ الَّذِينَ كَفَرُوا بِالْبَاطِلِ لِيُدْحِضُوا بِهِ الْحَقَّ ۖ وَاتَّخَذُوا آيَاتِي وَمَا أُنْذِرُوا هُزُوًا
Ati pe A ko ran awon Ojise nise (lasan) afi ki won je oniroo-idunnu ati olukilo. Awon t’o sai gbagbo si n fi iro satako nitori ki won le fi wo ododo. Won si so awon ayah Mi ati ohun ti A fi sekilo fun won di yeye
وَمَنْ أَظْلَمُ مِمَّنْ ذُكِّرَ بِآيَاتِ رَبِّهِ فَأَعْرَضَ عَنْهَا وَنَسِيَ مَا قَدَّمَتْ يَدَاهُ ۚ إِنَّا جَعَلْنَا عَلَىٰ قُلُوبِهِمْ أَكِنَّةً أَنْ يَفْقَهُوهُ وَفِي آذَانِهِمْ وَقْرًا ۖ وَإِنْ تَدْعُهُمْ إِلَى الْهُدَىٰ فَلَنْ يَهْتَدُوا إِذًا أَبَدًا
Ta si l’o sabosi ju eni ti won fi awon ayah Oluwa re seranti fun, ti o gbunri kuro nibe, ti o si gbagbe ohun ti owo re mejeeji ti siwaju? Dajudaju Awa fi ebibo bo okan won nitori ki won ma baa gbo o ye. A si fi edidi sinu eti won. Ti iwo ba pe won sinu imona, nigba naa won ko si nii mona laelae
وَرَبُّكَ الْغَفُورُ ذُو الرَّحْمَةِ ۖ لَوْ يُؤَاخِذُهُمْ بِمَا كَسَبُوا لَعَجَّلَ لَهُمُ الْعَذَابَ ۚ بَلْ لَهُمْ مَوْعِدٌ لَنْ يَجِدُوا مِنْ دُونِهِ مَوْئِلًا
Oluwa re, Alaforijin, Onikee, ti o ba je pe O maa fi ohun ti won se nise mu won ni, iba tete mu iya wa fun won. Sugbon akoko adehun (ajinde) wa fun won. Won ko si nii ri ibusasi kan leyin re

Choose other languages: