Quran Apps in many lanuages:

Surah Al-Kahf Ayahs #28 Translated in Yoruba

إِلَّا أَنْ يَشَاءَ اللَّهُ ۚ وَاذْكُرْ رَبَّكَ إِذَا نَسِيتَ وَقُلْ عَسَىٰ أَنْ يَهْدِيَنِ رَبِّي لِأَقْرَبَ مِنْ هَٰذَا رَشَدًا
Ayafi (ki o fi kun un pe) "ti Allahu ba fe." Se iranti Oluwa re nigba ti o ba gbagbe (lati so bee lasiko naa). Ki o si so (fun won) pe: “O rorun ki Oluwa mi to mi sona pelu eyi ti o sunmo ju eyi lo ni imona (fun yin).”
وَلَبِثُوا فِي كَهْفِهِمْ ثَلَاثَ مِائَةٍ سِنِينَ وَازْدَادُوا تِسْعًا
Won wa ninu iho apata won fun ogorun-un meta odun. Won tun lo alekun odun mesan-an
قُلِ اللَّهُ أَعْلَمُ بِمَا لَبِثُوا ۖ لَهُ غَيْبُ السَّمَاوَاتِ وَالْأَرْضِ ۖ أَبْصِرْ بِهِ وَأَسْمِعْ ۚ مَا لَهُمْ مِنْ دُونِهِ مِنْ وَلِيٍّ وَلَا يُشْرِكُ فِي حُكْمِهِ أَحَدًا
So pe: “Allahu nimo julo nipa ohun ti won lo (ninu iho apata). TiRe ni ikoko awon sanmo ati ile. Ki ni ko ri tan, ki si ni ko gbo tan! Ko si alaabo kan fun won leyin Re. Ko si fi eni kan se akegbe ninu idajo Re.”
وَاتْلُ مَا أُوحِيَ إِلَيْكَ مِنْ كِتَابِ رَبِّكَ ۖ لَا مُبَدِّلَ لِكَلِمَاتِهِ وَلَنْ تَجِدَ مِنْ دُونِهِ مُلْتَحَدًا
Ke ohun ti A fi ranse si o ninu Tira Oluwa re. Ko si eni ti o le yi awon oro Re pada. Iwo ko si le ri ibusasi kan yato si odo Re
وَاصْبِرْ نَفْسَكَ مَعَ الَّذِينَ يَدْعُونَ رَبَّهُمْ بِالْغَدَاةِ وَالْعَشِيِّ يُرِيدُونَ وَجْهَهُ ۖ وَلَا تَعْدُ عَيْنَاكَ عَنْهُمْ تُرِيدُ زِينَةَ الْحَيَاةِ الدُّنْيَا ۖ وَلَا تُطِعْ مَنْ أَغْفَلْنَا قَلْبَهُ عَنْ ذِكْرِنَا وَاتَّبَعَ هَوَاهُ وَكَانَ أَمْرُهُ فُرُطًا
Se suuru fun emi re lati wa pelu awon t’o n pe Oluwa won ni owuro ati ni asale, ti won n wa Oju rere Re. Ma se foju pa won re lati wa oso isemi aye (yii). Ma si se tele eni ti A mu okan re gbagbe iranti Wa. O tele ife-inu re; oro re si je aseju

Choose other languages: